Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌKÀNNÌ JW.ORG

Wo Fídíò Lórí JW.ORG

Wo Fídíò Lórí JW.ORG

Wo fídíò kan tàbí gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan. O lè dá a dúró, dá a pa dà sẹ́yìn tàbí kó o sún un síwájú.

 Wá Fídíò, Kó O sì Wò Ó

Lọ sí OHUN TÁ A NÍ > FÍDÍÒ kó o lè rí gbogbo fídíò tó wà, títí kan àwọn tá a ṣe ní ibi tá a ti ń gbé ètò Tẹlifíṣọ̀n JW jáde.

Yan ìsọ̀rí fídíò kan.

Ní ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, wàá rí àkójọ àwọn fídíò pẹ̀lú àkòrí tó bá a mú. Tó o bá fẹ́ rí fídíò púpọ̀ sí i ní ìsọ̀rí kan, tẹ bọ́tìnì tó wà ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì tàbí kó o tẹ bọ́tìnì Wo Gbogbo Ẹ̀.

Lo àwọn ọ̀nà tó wà nísàlẹ̀ yìí láti fi wo fídíò kan tàbí kó o fi ránṣẹ́ sí ẹnì kan:

  • Tẹ bọ́tìnì yìí lójú ẹ̀rọ rẹ kó o lè wo fídíò náà.

  • Tẹ bọ́tìnì Wà á jáde kó o lè wa fídíò náà jáde sórí ẹ̀rọ rẹ. (Àkíyèsí: Àwọn ẹ̀rọ kan máa gba pé kó o fi àwọn ètò ìṣiṣẹ́ míì sórí ẹ̀ kó o tó lè wa fáìlì èyíkéyìí jáde. Tó o bá ní ètò ìṣiṣẹ́ JW Library lórí ẹ̀rọ rẹ, ó máa dáa kó o lò ó láti fi wa àwọn fídíò tó o fẹ́ wà jáde, wàá sì lè máa wo àwọn fídíò náà láìsí íńtánẹ̀ẹ̀tì.)

  • Tẹ bọ́tìnì Fi ránṣẹ́ kó o lè fi ìlujá sí fídíò náà ránṣẹ́ sí ẹnì kan. Fún àlàyé síwájú sí i, wo “Fi Ìlujá Àpilẹ̀kọ, Fídíò Tàbí Ìtẹ̀jáde Kan Ránṣẹ́.”

  • Tó o bá fẹ́ wo fídíò náà ní èdè míì, yan èdè tó o fẹ́ lára àwọn èdè tó wà ní ibi tí àmì Èdè wa lẹ́gbẹ̀ẹ́ àkòrí fídíò náà.

 Wo Gbogbo Fídíò Tó Wà Ní Ìsọ̀rí Kan

Tẹ bọ́tìnì Lọ́kan-ò-jọ̀kan kó o kó o lè máa wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Ọ̀nà méjì lo lè gbà wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan:

  • Tẹ bọ́tìnì Gbádùn Gbogbo Ẹ̀ kó o lè wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan, bẹ̀rẹ̀ látorí àkọ́kọ́.

  • Tẹ bọ́tìnì Lọ́kan-ò-jọ̀kan kó o lè máa wo àwọn fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan lọ́kan-ò-jọ̀kan.

Àkíyèsí: Tó o bá ti wo gbogbo fídíò tó wà ní ìsọ̀rí kan tán, ó máa dáwọ́ dúró.

 Ṣe Fídíò Bó O Ṣe Fẹ́

Tó o bá ń wo fídíò kan lọ́wọ́, o lè ṣe é bó o ṣe fẹ́:

  • Tẹ bọ́tìnì yìí kí fídíò náà lè kún ojú ẹ̀rọ rẹ tàbí kó má kún ojú ẹ̀rọ.

  • Tẹ́ bọ́tìnì Dúró Ná kó o lè dá fídíò náà dúró.

  • Tẹ́ bọ́tìnì Máa Bá A Lọ kó o lè máa wo fídíò náà lọ.

  • O lè fa bọ́tìnì yìí síwájú tàbí sẹ́yìn sí ibi tó o bá fẹ́ wò nínú fídíò náà.

  • Tẹ bọ́tìnì Ìró Ohùn, kó o wá fà á sókè tàbí sí ìsàlẹ̀ kí ohùn tó ò ń gbọ́ lè ròkè tàbí wálẹ̀ sí i. Tó o bá ń lo fóònù, ó lè lo bọ́tìnì orí fóònù ẹ̀ láti fi mú kí ohùn náà lọ sókè tàbí wá sílẹ̀.

 Yan Irú Fídíò Tó O Fẹ́

Tẹ bọ́tìnì yìí kó o lè yan irú fídíò tó o fẹ́. (Àkíyèsí: Kì í ṣe gbogbo browser ló máa gbé bọ́tìnì yìí jáde.)

Kí ni àwọn nọ́ńbà yẹn dúró fún? Tí nọ́ńbà yẹn bá ṣe tóbi tó ní àwòrán ojú fídíò náà ṣe máa jáde dáadáa tó, bẹ́ẹ̀ náà ló sì ṣe máa jẹ íńtánẹ̀ẹ̀tì tó. Yan èyí tó bá bí íńtánẹ̀ẹ̀tì rẹ bá ṣe rí mú, tó bá ẹ̀rọ tó ò ń lò mú, tí kò sì ní ná ẹ lówó jù.

Àtẹ yìí ṣàlàyé bí nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan ṣe ń ṣiṣẹ́:

Nọ́ńbà

Bó Ṣe Ń Ṣiṣẹ́

240p

Èyí ló kéré jù. Ó dáa fún àwọn fóònù tí ojú wọn kéré.

360p

Èyí kéré díẹ̀. Ó dáa fún àwọn fóònù tí ojú wọn kéré.

480p

Èyí dáa. Ó dáa fún tablet, kọ̀ǹpútà àti àwọn tẹlifíṣọ̀n tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń lò.

720p

Èyí ni fídíò ojú ẹ̀ máa jáde dáadáa jù. Ó máa bá kọ̀ǹpútà tí ojú ẹ̀ fẹ̀ àti àwọn tẹlifíṣọ̀n ìgbàlódé tí ojú wọn fẹ̀ dáadáa ṣiṣẹ́.

Kí ló lè mú kí n mú yí nọ́ńbà tí mo mú pa dà? Tí íńtánẹ̀ẹ̀tì rẹ̀ kó bá fi bẹ́ẹ̀ lágbára, tó o wá rí i pé ṣe ni fídíò náà ń dákú tàbí tó ń fà, á dáa kó o lọ mú nọ́ńbà tó kéré sí èyí tó ò ń lò. Yan nọ́ńbà tó bá dáa jù fún kọ̀ǹpútà tàbí ẹ̀rọ rẹ. Tó o bá fẹ́ ṣọ́wó ná, yan nọ́ńbà tó kéré torí kò ní ná ẹ ní data tó pọ̀.

Tẹ bọ́tìnì yìí kó o lè máa rí ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ lójú fídíò náà ní èdè tí ò ń gbọ́. Bọ́tìnì yìí náà lo máa lò tí o kò bá fẹ máa rí ọ̀rọ̀ náà mọ́.

Àkíyèsí: Kì í ṣe gbogbo fídíò ló máa gbé ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ jáde.