Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 6, 2016
HUNGARY

Iléeṣẹ́ Holocaust Memorial Center Lórílẹ̀-èdè Hungary Ṣí Àmì Ẹ̀yẹ Kan Láti Fi Yẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Ìjọba Násì Pa Sí

Iléeṣẹ́ Holocaust Memorial Center Lórílẹ̀-èdè Hungary Ṣí Àmì Ẹ̀yẹ Kan Láti Fi Yẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Ìjọba Násì Pa Sí

ÌLÚ BUDAPEST, lórílẹ̀-èdè Hungary—Iléeṣẹ́ Holocaust Memorial Center nílùú Budapest ṣí àmì ẹ̀yẹ kan láti fi ṣèrántí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin tó fojú winá àtakò lásìkò ìjọba Násì. December 11, 2015 ni wọ́n ṣe ayẹyẹ tí wọ́n fi ṣí àmì ẹ̀yẹ náà.

Àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n fi rántí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin tí Ìjọba Násì pa nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.

Gbangba ni ẹgbẹ́ Arrow Cross Nazi Party lórílẹ̀-èdè Hungary ti pa àwọn ọkùnrin mẹ́rin náà, ìyẹn Lajos Deli, Antal Hönisch, Bertalan Szabό, àti János Zsondor. Ìlú Körmend àti Sárvár lórílẹ̀-èdè Hungary ni wọ́n ti pa wọ́n ní March 1945 torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Orúkọ wọn wà lára àmì ẹ̀yẹ náà, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó wà nínú Ìṣe 5:29, tó sọ pé, “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”

Dr. Csaba Latorcai tó jẹ́ igbákejì akọ̀wé ìjọba fún ọ̀rọ̀ pàtàkì láwùjọ ní orílẹ̀-èdè Hungary, ń sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ tí wọ́n fi ṣí àmì ẹ̀yẹ náà.

Nígbà tí Dr. Csaba Latorcai, tó jẹ́ igbákejì akọ̀wé ìjọba fún ọ̀rọ̀ pàtàkì láwùjọ, ń sọ̀rọ̀ nígbà tí ayẹyẹ náà bẹ̀rẹ̀, ó ní: “À ń fi àmì ẹ̀yẹ yìí rántí àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, . . . torí pé wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n rọ̀ mọ́ àṣẹ tó sọ pé ‘ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn,’ wọn ò sì gbé ohun ìjà láti fi pa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn aládùúgbò wọn torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè.”

Dr. Szabolcs Szita, ọ̀gá iléeṣẹ́ Holocaust Memorial Center, tóun náà sọ̀rọ̀ níbi ayẹyẹ tí wọ́n fi ṣí àmì ẹ̀yẹ náà sọ pé: “Àṣeyọrí ló jẹ́ fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá a ṣe ṣí àmì ẹ̀yẹ náà torí pé ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn èèyàn ò fi rántí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lára àwọn tó jìyà nígbà ìjọba Násì. Ìgbàgbọ́ àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́rin tí wọ́n pa náà ò yẹ̀, wọn ò sì yíhùn pa dà títí dójú ikú. Àpẹẹrẹ rere ni gbogbo wọn jẹ́ fún wa lónìí.”

Dr. Szabolcs Szita tó jẹ́ ọ̀gá iléeṣẹ́ Holocaust Memorial Center nílùú Budapest, ń ṣí ohun tí wọ́n fi bo àmì ẹ̀yẹ náà.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, tel. +1 718 560 5000

Hungary: András Simon, tel. +36 1 401 1118