Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ta tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jọ́jíà, tí wọ́n sì wọ aṣọ ìbílẹ̀ bá àwọn àlejò méjì ya fọ́tò níbi àpéjọ náà.

NOVEMBER 22, 2018
JỌ́JÍÀ

Àkànṣe Àpéjọ Àkọ́kọ́ Tó Wáyé Nílùú Tbilisi, ní Jọ́jíà

Àkànṣe Àpéjọ Àkọ́kọ́ Tó Wáyé Nílùú Tbilisi, ní Jọ́jíà

Tayọ̀tayọ̀ làwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin ní Jọ́jíà fi kí àwọn àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè méjìdínlógún (18) káàbọ̀ síbi àkànṣe àpéjọ “Jẹ́ Onígboyà”! tó wáyé ní Tbilisi, olú-ìlú Jọ́jíà, ní July 20-22, 2018. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tí àkànṣe àpéjọ máa wáyé ní Jọ́jíà. Ọ̀pọ̀ àsọyé tó ń gbéni ró, tó sì dá lórí Bíbélì ni wọ́n gbọ́ níbẹ̀, àwọn ará fìfẹ́ gba àwọn ará wọn lálejò, wọ́n sì ṣàfihàn àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ìtàn orílẹ̀-èdè náà.

Ibi tí wọ́n ti ṣe àpéjọ náà ni Olympic Palace, gbọ̀ngàn ìṣeré kan tó wà nílùú Tbilisi, iye àwọn tó sì péjọ síbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje ó lé méjì (7,002). Wọ́n ta àtagbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà sí ibi ọgọ́rin (80) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè náà, èyí mú kí àpapọ̀ àwọn tó gbádùn àpéjọ náà lé ní ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógún àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún (21,500). Ọ̀kan lára ohun mánigbàgbé tó wáyé ní àpéjọ náà ni àwọn igba ó lé mẹ́jọ (208) tó ṣe ìrìbọmi tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Yàtọ̀ sí àwọn àsọyé tó dá lórí Bíbélì tí wọ́n gbọ́, àwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè míì gbádùn bí àwọn ará Jọ́jíà ṣe ṣàfihàn àṣà ìbílẹ̀ wọn. Àwọn ará ní Jọ́jíà jó ijó ìbílẹ̀ fún wọn, wọ́n kọrin ilẹ̀ wọn, wọ́n tún ṣe oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn, wọ́n sì mú àwọn àlejò náà rìn yí ká àwọn ibi àtijọ́ nílùú Tbilisi.

Tamaz Khutsishvili tó jẹ́ aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì Jọ́jíà sọ pé: “Kì í kúkú ṣe pé a lómìnira ẹ̀sìn lọ títí lórílẹ̀-èdè wa. Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, àwọn aláṣẹ ìlú fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa, òun ló jẹ́ ká láǹfààní láti gba àwọn ará wa tó pọ̀ tó yìí lálejò ká lè jọ gbádùn àpéjọ yìí ní ìrọwọ́rọsẹ̀. A ò lè gbàgbé láé!”—Róòmù 15:7.

Ní July 20-22, 2018, iye àwọn tó wà níbi àkànṣe àpéjọ tó wáyé ní gbọ̀ngàn Olympic Palace jẹ́ 7,002. Àwọn 14,912 míì gbádùn àpéjọ náà láwọn ibòmíì tí wọ́n ta àtagbà ẹ̀ sí káàkiri orílẹ̀-èdè náà.

Arákùnrin Stephen Lett, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí, ló sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

Ọ̀kan lára ohun mánigbàgbé tó wáyé ní àkànṣe àpéjọ náà ni àwọn 208 tó ìrìbọmi, tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Itòsí àpáta kan tó wà nínú gbọ̀ngàn Olympic Palace ni wọ́n ṣe odò ìrìbọmi náà sí.

Wọ́n ta àtagbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà síbi ọgọ́rin (80) ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Àwọn arábìnrin tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jọ́jíà lọ pàdé ọ̀kan lára àlejò tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Ọ̀kan nínú àwọn arábìnrin náà dé fìlà tí wọ́n fi irun àgùntàn ṣe; wọ́n sábà máa ń wọ irú fìlà yìí láwọn apá ibì kan ní Jọ́jíà.

Wọ́n ṣe ètò kan tó lárinrin ní July 17 àti 18 ní Château Mukhrani, tó wà ní abúlé Mukhrani, nítòsí Tbilisi. Àwọn ará kọ orin ilẹ̀ Jọ́jíà níbẹ̀, wọ́n jó ijó ìbílẹ̀ fún wọn, wọ́n sì wo fídíò méjì tó dá lórí bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Jọ́jíà.

Àwọn ará ń jó ijó tí wọ́n ń pè ní Adjaruli (orúkọ yìí wá látinú orúkọ náà Adjara, tó jẹ́ orúkọ apá ibì kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà, nítòsí Òkun Dúdú). Wọ́n tún wọ aṣọ ìbílẹ̀ aláràbarà tí wọ́n máa ń wọ̀ lágbègbè yẹn láti fi gbé ijó náà lárugẹ.

Àwọn arákùnrin ń kọ orin ìbílẹ̀ kan bí wọ́n ṣe máa ń kọ ọ́ nígbà àtijọ́ ní Jọ́jíà.