Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 24, 2021
KÁNÁDÀ

A Rántí Àwọn Ará Wa Tó Nígbàgbọ́ ní Àgọ́ Tí Wọ́n Ti Ń Fipá Múni Ṣiṣẹ́ ní Kánádà

A Rántí Àwọn Ará Wa Tó Nígbàgbọ́ ní Àgọ́ Tí Wọ́n Ti Ń Fipá Múni Ṣiṣẹ́ ní Kánádà

Lọ́dún 1946, ìjọba orílẹ̀-èdè Kánádà dá àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láwọn àgọ́ tí wọ́n ti ń fipá múni ṣiṣẹ́ sílẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn àgọ́ yìí ló sì wà ní aṣálẹ̀ tó ṣòro dé ní Kánádà. Àwọn arákùnrin wa tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ni wọ́n fipá mú láti ṣiṣẹ́ láwọn àgọ́ yìí torí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Torí pé àwọn arákùnrin wa yìí nígboyà, wọ́n fara da ohun tí ojú wọn rí ní àgọ́ náà, ìyẹn sì mú kí ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára. Ó ti pé ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) tí wọ́n ti dá àwọn arákùnrin wa yìí sílẹ̀ láwọn àgọ́ náà. Don MacLean tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ṣì wà láàyè lára wọn sọ pé: “Gbogbo ohun tójú mi rí lásìkò tí ogun fi jà ti mú kí ìgbàgbọ́ mi túbọ̀ lágbára. Kò sígbà tí mo bá rántí tí mi ò kì í dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà.”