Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọkọ̀ àwọn ọlọ́pàá dí ibi tí wọ́n ń gbà gun afárá kan tí omi ti bò mọ́lẹ̀ ní Sainte-Marie-de-Beauce, lágbègbè Quebec

MAY 17, 2019
KÁNÁDÀ

Omíyalé Ṣẹlẹ̀ ní Kánádà

Omíyalé Ṣẹlẹ̀ ní Kánádà

Lórílẹ̀-èdè Kánádà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tó ń gbé ní agbègbè New Brunswick, Ontario, àti Quebec ni omíyalé ti lé kúrò nílé. Lágbègbè Quebec nìkan, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án (9,000) èèyàn ló ní láti kó kúrò níbi tí wọ́n ń gbé.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Kánádà sọ pé ní Quebec, ilé mẹ́rìnlélógójì (44) àwọn ará wa ló bà jẹ́. Ní New Brunswick àti Ontario, a ò tíì gbọ́ pé ó ba nǹkan kan jẹ́, àmọ́ omíyalé náà kò tíì dáwọ́ dúró.

Àwọn alábòójútó àyíká tó wà láwọn agbègbè tọ́rọ̀ kàn ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn alàgbà tó wà níbẹ̀ láti tu àwọn ará nínú. Bákan náà, aṣojú kan láti ẹ̀ka ọ́fíìsì lọ ṣẹ̀bẹ̀wò sáwọn apá ibi tí omíyalé náà ti pọ̀ gan-an kó lè fún wọn níṣìírí nípa tẹ̀mí. Ní agbègbè Beauce, àwọn ará ti palẹ̀ ìdọ̀tí àti àbàtà mọ́ kúrò nínú ogún (20) ilé tó jẹ́ tàwọn ará wa. Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Sainte-Marthe-sur-le-Lac, wọ́n ń ran àwọn tí ilé wọn bà jẹ́ lọ́wọ́.

Àdúrà wa ni pé kí àwọn ará wa tí àjálù yìí kàn má ṣe dẹ́kun láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tó jẹ́ ‘okun àti agbára wọn.’—Ẹ́kísódù 15:2.