Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JUNE 20, 2019
MEXICO

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Monterrey, Mẹ́síkò

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Tá A Ṣe ní 2019—Monterrey, Mẹ́síkò
  • Déètì: June 7 sí 9, 2019

  • Ibi Tá A Ti Ṣe É: Pápá ìṣeré BBVA Bancomer Stadium ní ìlú Monterrey, Mẹ́síkò

  • Èdè: Gẹ̀ẹ́sì, Èdè Adití ti Mẹ́síkò, Sípáníìṣì

  • Àwọn Ibi Tí Wọ́n Ta Àtagbà Rẹ̀ sí: Ibi méjìdínlógójì (38) ní orílẹ́-èdè mẹ́fà (Costa Rica, Guatemala, Honduras, Mẹ́síkò, Nicaragua àti Panama)

  • Àwọn Tó Wá: 39,099

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 393

  • Àwọn Tó Wá Láti Ìlẹ̀ Òkèèrè: 4,682

  • Áwọn Ẹ̀ka Ọ́fíísì Tó Wá: Ajẹntínà, Brazil, Kòlóńbíà, Faransé, Ítálì, Japan, Netherlands, Paraguay, Peru, Sípéènì, Amẹ́ríkà

  • Ìrírí: Roberto Valero tó jẹ́ aṣojú ìjọba ìlú Guadalupe lọ sí ibi tá a ti ṣe àpéjọ lọ́jọ́ Sátidé. Ó sọ pé: “Ohun tó ṣe pàtàkì jù sí ìjọba ilẹ̀ wa ni bí àwọn èeyàn á ṣe wà ní àlááfíà àti ààbò. Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kópa tó jọjú nínú mímú kí èyí ṣeé ṣe. Gbogbo ará ìlú yìí ló sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.”

 

Àwọn ará ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ ní pápákọ̀ òfúrufú Monterrey International Airport

Àwọn ará ń dé ibi tí wọ́n ti máa ṣe àpéjọ, òkè tí wọ́n ń pè ní Mount Silla wà níwájú

Arákùnrin Mark Sanderson, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn lọ́jọ́ Sunday

Ọkùnrin yìí ṣe ìrìbọmi nínú ọ̀kan lára àwọn odò mẹ́rin tó wà fún ìrìbọmi

Àwọn ará tó wá láti ìlẹ̀ òkèèrè ń fetí sílẹ̀ bí àpéjọ ṣé ń lọ lọ́wọ́

Àwọ́n tó wà lẹ́nu àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tí wọ́n wá láti ilẹ̀ òkèèrè ń juwọ́ sáwọn ará lọ́jọ́ tí àpéjọ parí

Ìdílé kan láti ìlú Apodaca ní Mẹ́síkò gbé àkọlé kan dání tó sọ pé, ‘A nífẹ̀ẹ́ yín’

Àwọn arábìnrin yìí ń wàásù ní ìlú Monterrey

Àwọn tó wá sí àpejọ náà ń gbádùn ijó àwọn tó wá láti àríwá Mẹ́síkò tí wọ́n máa ń pè ní Polka Norteña

Àwọn arábìnrin yìí ń jó ijó ìbílẹ̀ àwọn tó wá láti ìpińlẹ̀ Jalisco ní Mẹ́síkò