Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run?

Tó o bá fẹ́ mọ ẹnì kan, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tí wàá kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ ni pé, “Kí ni orúkọ rẹ?” Tó o bá bi Ọlọ́run ní ìbéèrè yẹn, ìdáhùn wo lo rò pé ó máa fún ẹ?

“Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.”​Aísáyà 42:8.

Ṣé o ti gbọ́ orúkọ yẹn rí? Ó ṣeé ṣe kó o má tíì gbọ́ ọ rí torí pé ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì kò fi bẹ́ẹ̀ lo orúkọ yẹn, àwọn míì ò sì lò ó rárá. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń fi orúkọ oyè náà “OLÚWA” rọ́pò rẹ̀. Síbẹ̀, orúkọ Ọlọ́run fara hàn ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Álífábẹ́ẹ̀tì mẹ́rin nínú èdè Hébérù ìyẹn YHWH tàbí JHVH, ló para pọ̀ di orúkọ náà, òun sì ni wọ́n túmọ̀ sí “Jèhófà” lédè Yorùbá.

Orúkọ Ọlọ́run fara hàn jálẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtúmọ̀ Bíbélì míì

Àkájọ ìwé Sáàmù nínú Òkun Òkú Ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní S.K., HÉBÉRÙ

Ìtúmọ̀ Bíbélì Tyndale 1530, GẸ̀Ẹ́SÌ

Ìtúmọ̀ ti Reina-Valera 1602, SÍPÁNÍÌṢÌ

Ìtúmọ̀ ti Union Version 1919, ÈDÈ CHINESE

ÌDÍ TÍ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN FI ṢE PÀTÀKÌ

Orúkọ náà ṣe pàtàkì sí Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Kò sí ẹnì kankan tó fún Ọlọ́run ní orúkọ yìí, òun ló fún ara rẹ̀. Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi fún àkókò tí ó lọ kánrin, èyí sì ni ìrántí mi láti ìran dé ìran.” (Ẹ́kísódù 3:15) Nínú Bíbélì, orúkọ Ọlọ́run ìyẹn Jèhófà fara hàn ju àwọn orúkọ oyè míì lọ, bí Olódùmarè, Baba, Olúwa, tàbí Ọlọ́run. Kódà ó tún fara hàn ju àwọn orúkọ míì lọ, bí Ábúráhámù, Mósè, Dáfídì, àti Jésù. Ìdí ni pé Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ orúkọ òun gangan. Bíbélì sọ pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”​—Sáàmù 83:18.

Orúkọ náà ṣe pàtàkì sí Jésù. Nínú àdúrà àwòṣe tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa, Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa bẹ Ọlọ́run pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Jésù fúnra rẹ̀ gbàdúrà pé: “Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” (Jòhánù 12:28) Bí Jésù ṣe máa fi ògo fún orúkọ Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù sí i, ìdí nìyẹn tó fi sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀.”​—Jòhánù 17:26.

Orúkọ náà ṣe pàtàkì sí àwọn tó mọ Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tó jọ́sìn Ọlọ́run láyé àtijọ́ mọ̀ pé tí wọ́n bá fẹ́ rí ààbò àti ìgbàlà, ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n mọ orúkọ Ọlọ́run. “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tí ó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, a sì dáàbò bò ó.” (Òwe 18:10) “Ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni yóò yè bọ́.” (Jóẹ́lì 2:32) Bíbélì fi hàn pé orúkọ Ọlọ́run máa fi ìyàtọ̀ sáàárín àwọn tó ń jọ́sìn Ọlọ́run àti àwọn tí kò sìn ín. “Nítorí gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.”​—Míkà 4:5; Ìṣe 15:14.

OHUN TÍ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN JẸ́ KÁ MỌ̀

Ó jẹ́ ká dá Ọlọ́run tòótọ́ mọ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé Bíbélì ló gbà pé orúkọ náà Jèhófà túmọ̀ sí “Alèwílèṣe.” Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́ ká mọ ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ nígbà tó ń sọ nípa ara rẹ̀ fún Mósè pé: “Èmi Yóò Jẹ́ Ohun Tí Èmi Yóò Jẹ́.” (Ẹ́kísódù 3:14) Torí náà, orúkọ yẹn ní ìtúmọ̀ tó jinlẹ̀ ju pé kéèyàn kàn pe Ọlọ́run ní Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Orúkọ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní agbára láti ṣe ohunkóhun, ó sì lè lo ìṣẹ̀dá rẹ̀ èyíkéyìí láti ṣe ohunkóhun tó bá ní lọ́kàn. Àwọn orúkọ oyè kan ń tọ́ka sí ipò Ọlọ́run, àṣẹ tó ní tàbí agbára rẹ̀. Àmọ́ orúkọ rẹ̀ gangan ló sọ irú ẹni tó jẹ́ ní pàtó àti ohun tó lè ṣe.

Ó jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa. Ìtúmọ̀ orúkọ Ọlọ́run fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ gbogbo nǹkan tí ó dá títí kan àwa èèyàn. Bí Ọlọ́run ṣe sọ orúkọ rẹ̀ fún wa jẹ́ kó dá wa lójú pé ó fẹ́ ká mọ òun. Kò retí pé ká béèrè lọ́wọ́ òun, fúnra rẹ̀ ló sọ ọ́ fún wa. Láìsí àní-àní, Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀ pé òun kì í ṣe àdììtú, àmọ́ òun jẹ́ ẹni tó wà lóòótọ́, a sì lè sún mọ́ òun.​—Sáàmù 73:28.

Tá a bá ń lo orúkọ Ọlọ́run, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àpẹẹrẹ kan rèé, ká sọ pé o pàdé ẹnì kan tó o fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí í bá ṣọ̀rẹ́, o wá sọ fún un pé orúkọ rẹ gangan lo fẹ́ kó máa pè ẹ́, àmọ́ gbogbo ìgbà tí ẹni náà bá ti rí ẹ, orúkọ míì ló máa ń pè ẹ́. Báwo ló ṣe máa rí lára ẹ? Ó ṣeé ṣe kó o máa rò ó pé ẹni náà kò ṣe tán láti di ọ̀rẹ́ rẹ. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí pẹ̀lú Ọlọ́run. Jèhófà ti sọ orúkọ rẹ̀ fún ọmọ aráyé, ó sì gbà wá níyànjú pé ká máa lò ó. Tá a bá ń lo orúkọ náà, ńṣe là ń jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé a fẹ́ sún mọ́ ọn. Kódà, Ọlọ́run máa ń fiyè sí àwọn tó ń ronú nípa orúkọ rẹ̀ tàbí àwọn tó ń pa orúkọ rẹ̀ mọ́ nínú ọkàn wọn!​—Málákì 3:16.

Tá a bá fẹ́ mọ Ọlọ́run, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ ni pé ká mọ orúkọ rẹ̀. Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó parí síbẹ̀. Ó tún yẹ ká mọ irú ẹni tó jẹ́.

KÍ NI ORÚKỌ ỌLỌ́RUN? Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. Orúkọ yẹn fi hàn pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ tó jẹ́ alèwílèṣe