Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÀWỌN TÓ Ń ṢỌ̀FỌ̀

Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́

Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́

Tó o bá ṣe ìwádìí nípa ohun tó lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́, àìmọye àbá lo máa rí, wọ́n sì gbéṣẹ́ ju ara wọn lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó fà á ni pé, ọ̀nà tí kálukú ń gbà ṣọ̀fọ̀ yàtọ̀ síra. Ohun tó ran ẹnì kan lọ́wọ́ lè má ran ẹlòmíì lọ́wọ́.

Síbẹ̀, àwọn ìlànà pàtàkì kan wà tó ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ gan-an. Àwọn tó máa ń gba àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nímọ̀ràn máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà náà dáadáa, wọ́n jẹ́ ìlànà àtayébáyé tó wà nínú ìwé ọgbọ́n náà Bíbélì, ọ̀pọ̀ ló sì ti rí i pé àwọn ìlànà yẹn wúlò gan-an.

1: JẸ́ KÍ ÀWỌN MỌ̀LẸ́BÍ ÀTÀWỌN Ọ̀RẸ́ RẸ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

  • Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan sọ pé èyí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tó lè ran àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ lọ́wọ́. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o dá nìkan wà. O tiẹ̀ lè máa bínú sí àwọn tó fẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa.

  • Má ṣe rò pé dandan ni káwọn èèyàn máa wà lọ́dọ̀ rẹ nígbà gbogbo, síbẹ̀ náà má ṣe lé àwọn èèyàn dà nù. Má gbàgbé pé o ṣì lè nílò ìrànlọ́wọ́ wọn tó bá yá. Fara balẹ̀ sọ ohun tó o fẹ́ káwọn èèyàn ṣe fún ẹ ní báyìí àti ohun tí o kò fẹ́.

  • Ronú dáadáa nípa ohun tó o nílò, kó o lè mọ ìgbà tó o fẹ́ káwọn èèyàn wà pẹ̀lú rẹ àti ìgbà tó o fẹ́ dá nìkan wà.

ÌLÀNÀ: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan . . . Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.”​—Oníwàásù 4:​9, 10.

2: Máa Jẹ Oúnjẹ Aṣaralóore, Kó O Sì Máa Ṣe Eré Ìdárayá

  • Tó o bá ń jẹ oúnjẹ aṣaralóore, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti kojú àìfararọ tí ẹ̀dùn ọkàn máa ń mú wá. Máa jẹ oríṣiríṣi èso, ẹ̀fọ́ àtàwọn oúnjẹ tó ní èròjà purotéènì àmọ́ tí kò fi bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rá nínú.

  • Máa mu omi dáadáa, àtàwọn ohun mímu míì tó ń ṣara lóore.

  • Tí o kò bá lè jẹ oúnjẹ púpọ̀ lẹ́ẹ̀kan náà, kọ́kọ́ jẹ díẹ̀, tó bá tún yá kó o jẹ sí i. O tún lè ní kí dókítà rẹ sọ àwọn oògùn tó ní èròjà oúnjẹ nínú tó o lè lò. a

  • O lè máa rìn kánmọ́kánmọ́ káàkiri tàbí kó o ṣe àwọn eré ìdárayá míì, èyí á jẹ́ kí ẹ̀dùn ọkàn ẹ fúyẹ́. Tó o bá ń ṣeré ìdárayá, ó lè jẹ́ kó o ráyè láti ronú nípa èèyàn rẹ tó kú tàbí kó jẹ́ kó o gbọ́kàn kúrò níbẹ̀.

ÌLÀNÀ: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.”​—Éfésù 5:29.

3: MÁA SÙN DÁADÁA

  • Gbogbo wa ló yẹ ká máa sùn dáadáa, àmọ́ ní pàtàkì àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀, torí pé ẹ̀dùn ọkàn tó máa ń bá wọn máa ń mú kó túbọ̀ rẹ̀ wọ́n.

  • Má ṣe máa mu ọtí líle àti kọfí lámujù, torí pé wọ́n lè má jẹ́ kó o rí oorun sùn.

ÌLÀNÀ: “Ẹ̀kúnwọ́ kan ìsinmi sàn ju ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára àti lílépa ẹ̀fúùfù.”​—Òwe 4:6.

4: ṢE OHUN TÓ MÁA RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́

  • Jẹ́ kó yé ẹ pé bí kálukú ṣe ń ṣọ̀fọ̀ yàtọ̀ síra. Torí náà, ìwọ fúnra rẹ lo máa mọ ohun táá ràn ẹ́ lọ́wọ́ jù lọ.

  • Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé táwọn bá fi ìmọ̀lara àwọn hàn síta, ó máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn fúyẹ́, àmọ́ ńṣe ni àwọn míì máa ń pa ẹ̀dùn ọkàn wọn mọ́ra. Èrò tó yàtọ̀ síra làwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní lórí ọ̀rọ̀ bóyá kí èèyàn fi ìmọ̀lára ẹ̀ hàn síta, tàbí kó pa á mọ́ra. Tó o bá rí i pé ó yẹ kó o sọ bó ṣe ń ṣe ẹ́ fẹ́nì kan, àmọ́ tí kò yá ẹ lára láti ṣe bẹ́ẹ̀, o lè bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀, bóyá kó o sọ díẹ̀ lára ẹ̀dùn ọkàn ẹ fún ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́ kan.

  • Àwọn kan ti wá rí i pé táwọn bá sunkún, ó máa ń jẹ́ kí ọkàn àwọn fúyẹ́, àmọ́ ní ti àwọn míì, ara wọn máa ń balẹ̀ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ bí wọn ò tiẹ̀ sunkún.

ÌLÀNÀ: “Ọkàn-àyà mọ ìkorò ọkàn ẹni.”​—Òwe 14:10.

5: YẸRA FÚN ÀWỌN NǸKAN TÓ LÈ ṢÀKÓBÁ FÚN ARA RẸ

  • Àwọn kan tó ń ṣọ̀fọ̀ rò pé àwọn lè fi ọtí tàbí oògùn olóró pa ìrònú rẹ́. Ńṣe ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣàkóbá fún ara wọn. Tí ara bá tiẹ̀ tù wọ́n, fún ìgbà díẹ̀ ni, ohun tó sì máa ń gbẹ̀yìn irú àṣà yẹn kì í dáa rárá. Ohun tí kò ní ṣàkóbá fún ẹ ni kó o fi pa ìrònú rẹ́.

ÌLÀNÀ: “Ẹ jẹ́ kí a wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin.”​—2 Kọ́ríńtì 7:1.

6: ṢÈTÒ ÀKÓKÒ RẸ

  • Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé ó ṣèrànwọ́ gan-an bí wọ́n ṣe pín àkókò tí wọ́n fi ń ṣọ̀fọ̀ sí méjì, (ìyẹn bí wọ́n ṣe ní ẹ̀dùn ọkàn àti ohun tí wọ́n ṣe láti kápá ẹ̀dùn ọkàn náà). Bí wọ́n ṣe ṣe é ni pé wọ́n máa ń ṣe àwọn nǹkan tó máa gbé ọkàn wọn kúrò nínú ẹ̀dùn ọkàn náà fún àkókò díẹ̀.

  • O lè rí i pé ara tù ẹ́ díẹ̀ tó o bá ń sún mọ́ àwọn èèyàn tàbí tó ò ń mú kí àárín ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ gún régé sí i, o tún lè kọ́ àwọn nǹkan tuntun tàbí kó o máa lọ síbi ìgbafẹ́.

  • Tó bá yá, wàá rí i pé nǹkan máa yí pa dà. O lè wá kíyè sí i pé àkókò tó o fi ń ṣe àwọn nǹkan tó máa jẹ́ kó o gbọ́kàn kúrò nínú ẹ̀dùn ọkàn rẹ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ó sì tún ń ṣe lemọ́lemọ́ sí i. Kó o tó mọ̀, wàá rí i pé ara ti bẹ̀rẹ̀ sí í tù ẹ́.

ÌLÀNÀ: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà sísunkún àti ìgbà rírẹ́rìn-ín; ìgbà pípohùnréré ẹkún àti ìgbà títọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri.”​—Oníwàásù 3:​1, 4.

7: MÁ ṢE JÓKÒÓ GẸLẸTẸ

  • Má ṣe jẹ́ kó pẹ́ kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀.

  • Tó o bá ti ní àkókò tó o máa ń sùn, àkókò iṣẹ́, àti àkókò tó o máa ń ṣe àwọn nǹkan míì, ó ṣeé ṣe kí ara rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í balẹ̀ pa dà.

  • Tó o bá ń fi àkókò rẹ ṣe àwọn nǹkan gidi, èyí á mú kí ẹ̀dùn ọkàn rẹ lọ sílẹ̀.

ÌLÀNÀ: “Kì í ṣe ìgbà gbogbo ni yóò máa rántí àwọn ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run tòótọ́ mú ọwọ́ rẹ̀ dí pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà rẹ̀.”​—Oníwàásù 5:20.

8: MÁ ṢE KÁNJÚ ṢE ÀWỌN ÌPINNU PÀTÀKÌ

  • Ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe ìpinnu pàtàkì ní gẹ́rẹ́ lẹ́yìn tí èèyàn wọn kú ló máa ń kábàámọ̀ àwọn ìpinnu náà.

  • Tó bá ṣeé ṣe, ṣe sùúrù dáadáa kó o tó kó lọ sí ibòmíì, kó o tó fi iṣẹ́ rẹ sílẹ̀, tàbí kó o tó sọ pé kò sóhun tó o fẹ́ fi ẹrù èèyàn rẹ tó ti kú ṣe.

ÌLÀNÀ: “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.”​—Òwe 21:5.

9: MÁ GBÀGBÉ ÈÈYÀN RẸ

  • Ọ̀pọ̀ àwọn tí èèyàn wọn kú ló gbà pé ó dáa kéèyàn máa ṣe àwọn nǹkan tí kò ní jẹ́ kó gbàgbé ẹni tó kú náà.

  • Ó lè jẹ́ ohun ìtùnú fún ẹ tó o bá ṣàkójọ àwọn fọ́tò tàbí àwọn ohun míì táá jẹ́ kó o máa rántí onítọ̀hún, tàbí kó o kọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wù ẹ́ kó o máa rántí.

  • Tọ́jú àwọn nǹkan tó lè rán ẹ létí àwọn nǹkan tó dáa nípa onítọ̀hún, kó o wá máa yẹ̀ wọ́n wò tó bá yá.

ÌLÀNÀ: “Rántí àwọn ọjọ́ láéláé.” ​—Diutarónómì 32:7.

10: MÁA ṢERÉ JÁDE

  • O lè rìnrìn-àjò lọ síbì kan kó o lọ sinmi.

  • Tí kò bá ṣeé ṣe fún ẹ láti lọ lo àkókò ìsinmi ọlọ́jọ́-púpọ̀, o lè gbìyànjú àwọn nǹkan míì fún bí ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, bóyá kó o fẹsẹ̀ rìn lọ sáwọn ibì kan, kó o lọ sí ibi tí wọ́n ń kó àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé sí tàbí kó o wakọ̀ lọ síbì kan.

  • Tó o bá gbìyànjú ohun tó yàtọ̀ sáwọn nǹkan tó o máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, ó lè mú kí ara tù ẹ́.

ÌLÀNÀ: “Ẹ máa bọ̀, ẹ̀yin fúnra yín, ní ẹ̀yin nìkan sí ibi tí ó dá, kí ẹ sì sinmi díẹ̀.” ​—Máàkù 6:31.

11: MÁA RAN ÀWỌN MÍÌ LỌ́WỌ́

  • Fi sọ́kàn pé gbogbo ìgbà tó o bá ran àwọn míì lọ́wọ́, ńṣe lara á máa tu ìwọ náà.

  • O lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ ń ṣọ̀fọ̀ ẹni tó kú náà, ó lè jẹ́ ẹbí tàbí ọ̀rẹ́ táwọn náà ní ẹ̀dùn ọkàn, tí wọ́n sì ń wá ẹni tó máa tù wọ́n nínú.

  • Bó o ṣe ń ran àwọn míì lọ́wọ́, tó o sì ń tù wọ́n nínú, inú rẹ á máa dùn, ayé rẹ á sì túbọ̀ nítumọ̀.

ÌLÀNÀ: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

12: RONÚ NÍPA ÀWỌN NǸKAN TÓ O KÀ SÍ PÀTÀKÌ JÙ

  • Tí èèyàn ẹni bá kú, ó lè jẹ́ kéèyàn wá ronú nípa ohun tó ṣe pàtàkì jù láyé.

  • Lo àkókò yìí láti ronú nípa ohun tó ò ń fi ayé rẹ ṣe.

  • Tó o bá rí i pé kì í ṣe àwọn nǹkan gidi lo kà sí pàtàkì jù, ṣe àtúnṣe tó bá yẹ.

ÌLÀNÀ: “Ó sàn láti lọ sí ilé ọ̀fọ̀ ju láti lọ sí ilé àkànṣe àsè, nítorí pé ìyẹn ni òpin gbogbo aráyé; ó sì yẹ kí alààyè fi í sí ọkàn-àyà rẹ̀.” ​—Oníwàásù 7:2.

Òótọ́ ni pé kò sí nǹkan tó lè mú ẹ̀dùn ọkàn rẹ kúrò pátápátá. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn tí èèyàn wọn kú ti jẹ́rìí sí i pé tí èèyàn bá gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì kan, bí irú àwọn tá a sọ nínú àpilẹ̀kọ yìí, ó máa ń mú kí ara tuni. Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan miì wà tó o lè ṣe àmọ́ tá ò sọ̀rọ̀ nípa wọn. Àmọ́, tó o bá gbìyànjú àwọn kan lára àwọn àbá yìí, wàá rí i pé ara máa tù ẹ́ gan-an.

a Ìwé ìròyìn Jí! kì í sọ irú ìtọ́jú pàtó tó yẹ kẹ́nì kan gbà.