Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbé Pẹ̀lú Ẹ̀dùn-Ọkàn Mi?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbé Pẹ̀lú Ẹ̀dùn-Ọkàn Mi?

“MO NÍMỌ̀LÁRA ìkìmọ́lẹ̀ tí ó pọ̀ jọjọ láti tẹ àwọn ìmọ̀lára mi rì,” ni Mike ṣàlàyé ni rírántí ikú baba rẹ̀. Fún Mike, títẹ ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ rì ni ohun tí ó túmọ̀sí láti ṣe bí ọkùnrin. Síbẹ̀ nígbà tí ó yá ó wá mọ̀ pé òun kò tọ̀nà. Nítorí náà nígbà tí ọ̀rẹ́ Mike pàdánù baba rẹ̀ àgbà, Mike mọ ohun tí ó yẹ láti ṣe. Ó sọ pé: “Ní àwọn ọdún mélòókan sẹ́yìn, ǹ bá ti fi ọwọ́ lù ú pẹ́pẹ́ ní èjìká kí n sì wí pé, ‘Ṣe bí ọkùnrin.’ Ṣùgbọ́n nísinsìnyí mo fi ọwọ́ ba ọwọ́ rẹ̀ mo sì sọ pé, ‘Ní ìmọ̀lára tí ó yẹ kí o ní. Yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀. Bí o bá fẹ́ kí n máa lọ èmi yóò máa lọ. Bí o bá fẹ́ kí n dúró, èmi yóò dúró. Ṣùgbọ́n máṣe fòyà láti nímọ̀lára.’”

MaryAnne pẹ̀lú ní ìkìmọ́lẹ̀ láti tẹ àwọn ìmọ̀lára rẹ̀ rì nígbà tí ọkọ rẹ̀ kú. Òun rántí pé: “Mo dààmú gidigidi nípa jíjẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn ẹlòmíràn, débi tí n kò fi gba araàmi láyè láti nímọ̀lára tí ó yẹ. Ṣùgbọ́n mo kẹ́kọ̀ọ́ níkẹyìn pé gbígbìyànjú láti jẹ́ orísun okun fún àwọn ẹlòmíràn kò ràn mí lọ́wọ́. Mo bẹ̀rẹ̀síí yẹ ipò mi wò mo sì sọ pé, ‘Sọkún bí ìwọ yóò bá sọkún. Máṣe gbìyànjú láti jẹ́ ọ̀dájú. Tú u jáde kúrò lára.’”

Nítorí náà Mike àti MaryAnne dámọ̀ràn pé: Fi araàrẹ sílẹ̀ láti kẹ́dùn! Wọ́n sì tọ̀nà. Èéṣe? Nítorí pé kíkẹ́dùn jẹ́ ìtúsílẹ̀ èrò-ìmọ̀lára pípọndandan. Títú ìmọ̀lára rẹ jáde lè lé ìkìmọ́lẹ̀ tí o wà lábẹ́ rẹ̀ lọ. Bí òye àti ìsọfúnni tí ó péye bá pẹ̀lú èrò-ìmọ̀lára tí a fihàn lọ́nà ti ẹ̀dá, yóò mú kí o fi ìmọ̀lára rẹ sí àyè tí ó tọ́.

Níti tòótọ́, kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó ń fi ẹ̀dùn-ọkàn hàn ní irú ọ̀nà kan náà. Àwọn kókó bíi bóyá ẹni tí a fẹ́ràn náà kú lójijì tàbí ikú náà wá lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ lè nípalórí ìhùwàpadà èrò-ìmọ̀lára àwọn aláṣẹ̀yìndè. Ṣùgbọ́n ohun kan dájú: Títẹ ìmọ̀lára rẹ rì lè léwu níti ara àti níti èrò-ìmọ̀lára. Títú ẹ̀dùn-ọkàn rẹ jáde ń ṣe ara lóore lọ́pọ̀lọpọ̀. Báwo? Ìwé Mímọ́ ní àwọn ìmọ̀ràn tí ó gbéṣẹ́.

Títú Ẹ̀dùn-Ọkàn Jáde​—Báwo?

Sísọ̀rọ̀ lè jẹ́ ìtúsílẹ̀ arannilọ́wọ́. Tẹ̀lé ikú gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́wẹ̀wàá, àti àwọn ọ̀ràn ìbànújẹ́ ara-ẹni mìíràn, babańlá ìgbàanì Jobu sọ pé: “Agara ìwà ayé mi dá mi tán, èmi ó tú àròyé mi sóde lọ́dọ̀ mi, èmi ó máa sọ nínú kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.” (Jobu 1:2, 18, 19; 10:1) Jobu kò lè pa àròyé rẹ̀ mọ́ra mọ́. Òun níláti tú u jáde; òun níláti ‘sọ̀rọ̀.’ Lọ́nà kan náà, òṣèré ọmọ England náà Shakespeare kọ̀wé nínú eré Macbeth pé: “Sọ ìbànújẹ́ rẹ jáde; wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ ni ẹ̀dùn-ọkàn tí a kò sọ̀ síta ń kó ìdààmú báni tí ó sì ń pinnilẹ́mìí.”

Nítorí náà sísọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀lára rẹ fún “ọ̀rẹ́” tòótọ́ tí yóò fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àti pẹ̀lú ìbákẹ́dùn fetísílẹ̀ lè mú ìtura díẹ̀ wá. (Owe 17:17) Sísọ àwọn ìrírí àti ìmọ̀lára lọ́rọ̀ sábà máa ń mú kí ó rọrùn láti lóye wọn àti láti kojú wọn. Bí olùfetísílẹ̀ náà bá sì jẹ́ ẹni tí ọ̀fọ̀ ti ṣẹ̀ rí tí ó ti kojú àdánù rẹ̀ lọ́nà gbígbéṣẹ́, ó lè ṣeéṣe kí ìwọ rí àwọn àbá tí ó gbéṣẹ́ gbà lórí bí o ṣe lè kojú rẹ̀. Nígbà tí ọmọ rẹ̀ kú, ìyá kan ṣàlàyé ìdí tí ó fi ṣèrànwọ́ láti bá obìnrin mìíràn tí ó ti kojú irú òfò kan náà sọ̀rọ̀: “Láti mọ̀ pé ẹlòmíràn ti faragbá ohun kan náà, tí ó sì ti là á já, àti pé ó ṣì wàláàyè tí ipò nǹkan sì ń lọ déédéé fún un lẹ́ẹ̀kan síi jẹ okun fún mi.”

Àwọn àpẹẹrẹ inú Bibeli fihàn pé ṣíṣe àkọsílẹ̀ ìmọ̀lára rẹ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ ẹ̀dùn-ọkàn rẹ jáde

Kí ni bi sísọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀lára rẹ kò bá rọ̀ ọ́ lọ́rùn? Lẹ́yìn ikú Saulu àti Jonatani, Dafidi kọ orin arò kan tí ó runisókè jọjọ nínú èyí tí òun tú ẹ̀dùn-ọkàn rẹ̀ jáde. Àkọsílẹ̀ ọ̀fọ̀ yìí níkẹyìn wá di apákan àkọsílẹ̀ Bibeli ti ìwé Samueli Keji. (2 Samueli 1:17-27; 2 Kronika 35:25) Lọ́nà kan náà, àwọn kan ri pé ó rọrùn jùlọ láti ṣàlàyé araawọn ní kíkọ ọ́ sílẹ̀. Opó kan ròyìn pé òun yóò ṣe àkọsílẹ̀ ìmọ̀lára òun àti ní àwọn ọjọ́ mélòókan lẹ́yìn náà òun yóò ka ohun tí òun ti kọ. Ó rí èyí gẹ́gẹ́ bí ìtúsílẹ̀ aṣèrànwọ́.

Bóyá nípa sísọ̀rọ̀ tàbí kíkọ ọ́ sílẹ̀, sísọ àwọn ìmọ̀lára rẹ jáde lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti tú ẹ̀dùn-ọkàn rẹ jáde. Ó tún ṣèrànlọ́wọ́ láti yanjú àwọn àṣìlóye. Ìyá kan tí ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ sọ pé: “Èmi àti ọkọ mi ti gbọ́ nípa àwọn tọkọtaya tí wọ́n kọ araawọn sílẹ̀ lẹ́yìn pípàdánù ọmọ kan, a kò sì fẹ́ kí ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí wa. Nítorí náà nígbàkigbà tí a bá bínú, tí a fẹ́ láti dẹ́bi fún ẹnìkínní kejì, a óò jọ jíròrò rẹ̀. Mo ronú pé a túbọ̀ súnmọ́ra pẹ́kípẹ́kí nípa ṣíṣe ìyẹn.” Nípa bẹ́ẹ̀, jíjẹ́ kí ìmọ̀lára rẹ di mímọ̀ lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti lóye pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ jọ ń ṣàjọpín àdánù kan náà, àwọn mìíràn lè fi ẹ̀dùn-ọkàn hàn lọ́nà tí ó yàtọ̀​—⁠ní ìwọ̀n ti wọn àti ní ọ̀nà ti wọn.

Ohun mìíràn tí ó lè mú kí títú ẹ̀dùn-ọkàn jáde túbọ̀ rọrùn ni sísọkún. “Ìgbà sísọkún” wà, ni Bibeli wí. (Oniwasu 3:​1, 4) Dájúdájú ikú ẹnìkan tí a fẹ́ràn máa ń mú irú ìgbà bẹ́ẹ̀ wá sórí wa. Dída omije ẹ̀dùn-ọkàn dàbí apá pípọndandan fún ọ̀nà ìgbà rí ìwòsàn.

Ọ̀dọ́bìnrin kan ṣàlàyé bí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan ti ṣe ràn án lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀ nígbà tí ìyá rẹ̀ kú. Ó rántí pé: “Ìgbà gbogbo ni ọ̀rẹ́ mi ń wà pẹ̀lú mi. Ó bá mi sọkún. Ó bá mi sọ̀rọ̀. Mo lè fi èrò-ìmọ̀lára mi hàn ni gbangba, ìyẹn sì ṣe pàtàkì fún mi. Sísọkún kò tì mí lójú.” (Wo Romu 12:15.) Bẹ́ẹ̀ sì ni omije rẹ kò níláti kó ìtìjú bá ọ. Gẹ́gẹ́ bí a ti ríi, Bibeli kún fún àpẹẹrẹ àwọn ọkùnrin àti obìnrin ìgbàgbọ́​—⁠tí Jesu Kristi pẹ̀lú​—tí wọ́n da omije ẹ̀dùn-ọkàn ní gbangba láìsí ìtìjú èyíkéyìí.​—Genesisi 50:3; 2 Samueli 1:11, 12; Johannu 11:33, 35.

Ní gbogbo àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kẹ́dùn mọrírì rírí ìtùnú gbà

O lè ríi pé fún àkókò kan àwọn èrò-ìmọ̀lára rẹ kò dàbí èyí tí ó ṣeé lóye. Omije lè máa dà láìsí ìkìlọ̀ ṣáájú. Opó kan ríi pé lílọ sí ilé ìtajà (ohun kan tí ó sábà máa ń ṣe pẹ̀lú ọkọ rẹ̀) lè fa ẹkún fún un, ní pàtàkì, nígbà tí, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, tí ó bá fẹ́ nawọ́ gan oúnjẹ kan tí ó jẹ́ èyí tí ọkọ rẹ̀ gbádùn jùlọ. Mú sùúrù fún araàrẹ. Má sì ṣe rò pé o níláti dá omije náà dúró. Rántí pé wọ́n bójúmu wọ́n sì jẹ́ apá pípọndandan fún fífi ẹ̀dùn-ọkàn hàn.

Kíkojú Ẹ̀bi

Gẹ́gẹ́ bí a ti mẹ́nubà á níṣàájú, àwọn kan ní ìmọ̀lára ẹ̀bi lẹ́yìn pípàdánù ẹnìkan tí wọ́n fẹ́ràn nínú ikú. Èyí lè ṣèrànwọ́ láti ṣàlàyé ẹ̀dùn-ọkàn lílégbákan ọkùnrin olóòótọ́ nì Jakobu nígbà tí a mú kí ó gbàgbọ́ pé ọmọkùnrin rẹ̀ Josefu ni “ẹranko búburú” ti pajẹ. Jakobu funraarẹ̀ ni ó rán Josefu jáde láti lọ wo àlàáfíà àwọn arákùnrin rẹ̀. Nítorí náà ó ṣeéṣe kí ìmọ̀lára ẹ̀bi bíi ‘Èéṣe ti mo fi rán Josefu jáde ní òun nìkan? Èéṣe ti mo fi rán an lọ sí àgbègbè ti ẹranko ẹhanna pọ̀ sí?’ máa dá Jakobu lóró.​—Genesisi 37:33-35.

Bóyá o nímọ̀lára pé àwọn àìbìkítà tó kan ní ìhà ọ̀dọ̀ rẹ dákún ikú olólùfẹ́ rẹ. Ní mímọ̀ pé ẹ̀bi náà​—⁠bóyá gidi tàbí àronúwòye​—jẹ́ ìhùwàpadà sí ẹ̀dùn-ọkàn lọ́nà bíbójúmu lè ṣèrànwọ́ nínú araarẹ̀. Níhìn-⁠ín pẹ̀lú, máṣe rò pé o níláti pa ìmọ̀lára náà mọ́ra. Sísọ̀rọ̀ nípa ẹ̀bi tí o rò pé o ní lè pèsè ìtura tí o nílò níti gidi gan-⁠an.

Bí ó ti wù kí ó rí, mọ̀ dájú pé kò sí bí a ṣe lè fẹ́ràn ẹnìkan tó, a kò lè ṣàkóso ìgbésí-ayé rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè dènà “ìgbà àti [èèṣì]” láti ṣubú tẹ àwọn tí a fẹ́ràn. (Oniwasu 9:11) Yàtọ̀ sí ìyẹn, kò sí iyèméjì pé ète tí o ní kò burú. Fún àpẹẹrẹ, níti ṣíṣàì tètè rí dókítà, ìwọ ha gbèrò pé kí olólùfẹ́ rẹ ṣàìsàn kí ó sì kú bí? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́! Nígbà náà ìwọ ha jẹ̀bi níti gidi fún jíjẹ́ okùnfà ikú ẹni náà bí? Rárá.

Ìyá kan kọ́ láti kojú ẹ̀bi tí ó ní lẹ́yìn tí ọmọbìnrin rẹ̀ kú nínú ìjàm̀bá mọ́tò. Ó sọ pé: “Mo ní ìmọ̀lára ẹ̀bi pé mo rán an jáde. Ṣùgbọ́n mo wa ri pé kò bọ́gbọ́nmu rárá láti ronú lọ́nà yẹn. Kò sí ohun tí ó burú nínú rírán an jáde pẹ̀lú baba rẹ̀ láti lọ ra àwọn nǹkan. Ó wulẹ̀ jẹ́ jàm̀bá burúkú ni.”

‘Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ nǹkan ni ó wà tí ǹ bá fẹ́ kí n ti sọ tàbí ṣe,’ ni ìwọ lè sọ. Òtítọ́ ni, ṣùgbọ́n ta ni nínú wa tí ó lè sọ pé a ti jẹ́ baba, ìyá, tàbí ọmọ pípé? Bibeli rán wa létí pé: “Nínú ohun púpọ̀ ni gbogbo wa ń ṣì í ṣe. Bí ẹnìkan kò bá ṣì í ṣe nínú ọ̀rọ̀, òun náà ni ẹni pípé.” (Jakọbu 3:2; Romu 5:12) Nítorí náà tẹ́wọ́gba òtítọ́ náà pé o jẹ́ aláìpé. Jíjàràndùn lórí onírúurú “ìbáṣepé” kì yóò yí ohunkóhun padà, ṣùgbọ́n ó lè fawọ́ ìkọ́fẹpadà rẹ sẹ́yìn.

Bí o bá ní àwọn ìdí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ láti gbàgbọ́ pé ẹ̀bi rẹ jẹ́ gidi, tí kìí ṣe èyí tí o ronúwòye, nígbà náà gbé kókó tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún mímú ẹ̀bi kúrò yẹ̀wò​—⁠ìdáríjì láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Bibeli mú un dá wa lójú pé: “Oluwa, ìbáṣepé kí ìwọ kí ó máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Oluwa, ta ni ìbá dúró? Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ.” (Orin Dafidi 130:3, 4) O kò lè padà sẹ́yìn láti yí ohunkóhun padà. Bí ó ti wù kí ó rí, o lè bẹ Ọlọrun fún ìdáríjì fún àwọn àṣìṣe tí ó ti kọjá. Kí ni ó tún kù ní ṣíṣe? Ó dára, bí Ọlọrun bá ṣèlérí láti gbàgbé àwọn àṣìṣe rẹ tí ó ti kọjá, ṣe kò yẹ kí ìwọ pẹ̀lú dáríji araàrẹ?​—Owe 28:13; 1 Johannu 1:9.

Kíkojú Ìbínú

Ìwọ ha ń bínú, bóyá sí àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì, àwọn ọ̀rẹ́, tàbí sí ẹni tí ó kú náà pàápàá? Mọ̀ dájú pé èyí pẹ̀lú jẹ́ ìhùwàpadà tí ó wọ́pọ̀ sí òfò. Bóyá ìbínú rẹ bá ẹ̀dùn-ọkàn tí ó nímọ̀lára rẹ̀ rìn lọ́nà ti ẹ̀dá ni. Òǹkọ̀wé kan sọ pé: “Kìkì nípa mímọ ìbínú náà​—⁠kìí ṣe ní gbígbégbèésẹ̀ lé e lórí ṣùgbọ́n mímọ̀ pé o nímọ̀lára rẹ̀​—⁠ni ìwọ fi lè yèbọ́ lọ́wọ́ ipá aṣèparun rẹ̀.”

Ó tún lè ṣèrànwọ́ láti fi ìbínú rẹ hàn tàbí ṣàjọpín rẹ̀. Báwo? Dájúdájú kìí ṣe nípa fífaraya. Bibeli kìlọ̀ pé ìbínú tí a fà gùn léwu. (Owe 14:29, 30) Ṣùgbọ́n ìwọ lè rí ìtùnú nínú sísọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan tí ó lóye. Àwọn kan sì ríi pé eré-ìdárayá àṣekára nígbà ti wọ́n bá ń bínú jẹ́ ìtúsílẹ̀ aṣèrànwọ́.​—⁠Wo Efesu 4:25, 26 pẹ̀lú.

Nígbà tí ó ṣe pàtàkì láti nàtán kí o sì jẹ́ aláìlábòsí nípa ìmọ̀lára rẹ, ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ kan yẹ. Ìyàtọ̀ gidigidi wà láàárín fífi ìmọ̀lára rẹ hàn àti fífi ìkanra rẹ̀ mọ́ àwọn ẹlòmíràn. Kò sí ìdí láti dẹ́bi fún àwọn ẹlòmíràn fún ìbínú àti ìjákulẹ̀ rẹ. Nítorí náà fiyèsí sísọ ìmọ̀lára rẹ jáde, ṣùgbọ́n kìí ṣe ní ọ̀nà ìkanramọ́ni. (Owe 18:21) Àrànṣe títayọ kan wà láti lè kojú ẹ̀dùn-ọkàn, a óò sì jíròrò rẹ̀ nísinsìnyí.

Ìrànlọ́wọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Ọlọrun

Bibeli mú un dá wa lójú pé: “Oluwa ń bẹ létí ọ̀dọ̀ àwọn tíí ṣe oníròbìnújẹ́ ọkàn; ó sì gba irú àwọn tíí ṣe onírora ọkàn là.” (Orin Dafidi 34:18) Bẹ́ẹ̀ni, ju ohunkóhun mìíràn lọ, ipò-ìbátan kan pẹ̀lú Ọlọrun lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú ikú ẹnìkan tí ìwọ fẹ́ràn. Báwo? Gbogbo àwọn àbá gbígbéṣẹ́ tí a ti fi fún ọ títí di ìsinsìnyí wà ní ìbámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli. Fífi wọ́n sílò lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti kojú rẹ̀.

Ní àfikún síi, máṣe fojúkéré ìníyelórí àdúrà. Bibeli rọ̀ wá pé: “Kó ẹrù rẹ lọ sí ara Oluwa, òun ni yóò sì mú ọ dúró.” (Orin Dafidi 55:22) Bí sísọ ìmọ̀lára rẹ jáde fún ọ̀rẹ́ abánikẹ́dùn kan bá lè ṣèrànwọ́, mélòómélòó ni títú ọkàn-àyà rẹ jáde fún “Ọlọrun ìtùnú gbogbo” yóò ti ṣèrànwọ́ tó!​—2 Korinti 1:3.

Kìí ṣe pé àdúrà wulẹ̀ ń mú kí ara wa yágágágá síi. Ẹni “tí ń gbọ́ àdúrà” ṣèlérí láti fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó fi tọkàntọkàn béèrè fún un. (Orin Dafidi 65:2; Luku 11:13) Ẹ̀mí mímọ́ tàbí ipá agbékánkán ṣiṣẹ́ Ọlọrun, lè pèsè “agbára tí ó rékọjá ti ẹ̀dá” tí o nílò láti la ọjọ́ dé ọjọ́ já. (2 Korinti 4:7, NW) Rántí pé: Ọlọrun lè ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin lọ́wọ́ láti farada ìṣòro èyíkéyìí àti gbogbo ìṣòro tí wọ́n lè dojúkọ.

Obìnrin kan tí ó pàdánù ọmọ kan nínú ikú rántí bí agbára àdúrà ti ran òun àti ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ jálẹ̀ gbogbo àkókò òfò wọn. Ó ṣàlàyé pé, “Bí a bá wà nínú ilé ní alẹ́ ti ẹ̀dùn-ọkàn náà sì ga pelemọ, a ó gbàdúrà sókè papọ̀.” Ó ń bá ọ̀rọ̀ lọ pé: “Ìgbà àkọ́kọ́ tí a níláti ṣe ohun kan láìsí i níbẹ̀​—⁠ìpàdé ìjọ tí a kọ́kọ́ lọ, àpéjọpọ̀ tí a kọ́kọ́ lọ​—⁠a gbàdúrà fún okun. Nígbà ti a jí ni òwúrọ̀ tí ó sì dàbí ẹni pé ìjótìítọ́ rẹ̀ kò ṣeé mu mọ́ra, a gbàdúrà sí Jehofa láti ràn wá lọ́wọ́. Fún ìdí mélòókan, ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ adaniláàmú fún mi láti dánìkan wọnú ilé. Nítorí náà nígbàkigbà tí mo bá wá sílé ní èmi nìkan, èmi yóò wulẹ̀ gbàdúrà sí Jehofa láti jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́ láti ní irú ìparọ́rọ́ kan.” Obìnrin adúróṣinṣin yẹn gbàgbọ́ lọ́nà títọ́ tí ó sì fẹsẹ̀múlẹ̀ pé àwọn àdúrà wọ̀nyẹn mú ìyàtọ̀ wá. Ìwọ pẹ̀lú lè ríi pé ní ìdáhùnpadà sí àdúrà onítẹpẹlẹmọ́ rẹ, ‘àlàáfíà Ọlọrun tí ó ju ìmọ̀ràn gbogbo lọ, yóò ṣọ́ ọkàn àti èrò rẹ.’​—Filippi 4:6, 7; Romu 12:12.

Ìrànlọ́wọ́ tí Ọlọrun ń pèsè ń mú ìyàtọ̀ wá níti gidi. Aposteli Paulu tí ó jẹ́ Kristian sọ pé Ọlọrun “ń tù wá nínú ní gbogbo wàhálà wa, nípa ìtùnú náà tí a fi ń tu àwa tìkáraawa nínú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, kí àwa kí ó lè máa tu àwọn tí ó wà nínú wàhálà-kí-wàhálà nínú.” Nítòótọ́, kò mú ìrora náà kúrò, ṣùgbọ́n ó lè mú kí ó rọrùn láti faradà. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ìwọ kì yóò sọkún mọ́ tàbí pé ìwọ yóò gbàgbé olólùfẹ́ rẹ. Ṣùgbọ́n o lè kọ́fẹpadà. Bí o sì ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ohun tí o ti faragbá lè mú kí o túbọ̀ jẹ́ olóye àti abánikẹ́dùn nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kojú irú òfò kan náà.​—2 Korinti 1:4.