Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Won Nifee Awon Ara Won

Won Nifee Awon Ara Won

Ìbísí Tó Wáyé Mú Ká Nílò Ilé Ẹ̀kọ́ Tuntun

Jèhófà bù kún iṣẹ́ àṣekára táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Lọ́dún 1994, ìpíndọ́gba iye akéde Ìjọba Ọlọ́run tó wà lórílẹ̀-èdè náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún àti ọ̀tàlélọ́ọ̀ọ́dúnrún dín mẹ́fà [16,354], iye ìjọ sì jẹ́ igba àti mọ́kàndínlọ́gọ́ta [259]. Ìbísí kíkàmàmà tó ń wáyé yìí mú ká túbọ̀ nílò àwọn alàgbà àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó kúnjú ìwọ̀n. Ọdún yẹn náà ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká máa ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ [MTS], tó wá di Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run báyìí, ní Orílẹ̀-èdè Dominican.

Ní oṣù October, ọdún 2011, nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tí wọ́n ti ṣe lórílẹ̀-èdè náà. Ní báyìí, ó lé ní ìdajì lára wọn tó ti wà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Àwọn mọ́kànléláàádọ́rin [71] jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe, àwọn márùn-ún sì jẹ́ alábòójútó àyíká. Inú ẹ̀ka ọ́fíìsì ni wọ́n ti ṣe kíláàsì mẹ́wàá àkọ́kọ́, àmọ́ látorí kíláàsì kọkànlá, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ilé tá a dìídì kọ́ fún ilé ẹ̀kọ́ náà nílùú Villa González.

“Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tọ́jú Àwọn Ará Wọn”

Ní September 22, ọdún 1998, ìjì líle kan tí wọ́n pè ní Georges ṣọṣẹ́ káàkiri Orílẹ̀-èdè Dominican, ó sì ba ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan jẹ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló di aláìnílé, àwọn tó kú sì lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300]. Ìgbìmọ̀ Ìkọ́lé Ẹlẹ́kùnjẹkùn ran Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù lọ́wọ́ láti ṣètò Gbọ̀ngàn Ìjọba kan nílùú La Romana tí wọ́n á ti máa pín àwọn ohun tí wọ́n á fi ṣèrànwọ́. Nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] èèyàn ló yọ̀ǹda ara wọn láti ṣèrànwọ́ títí kan àwọn ará tó wá láti orílẹ̀-èdè mẹ́rìndínlógún [16] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Lápapọ̀, Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́tàlélógún [23] àti ẹgbẹ̀rin [800] ilé tó jẹ́ ti àwọn ará wa la tún kọ́ tàbí tún ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ìbànújẹ́ bá arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ti dàgbà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Carmen nígbà tí ìjì líle náà ba ilé rẹ̀ tó ti ń gbé fún ọdún méjìdínlógójì [38] jẹ́. Àmọ́, ìdùnnú ṣubú láyọ̀ fún un nígbà tí àwọn arákùnrin mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] dé láti wá bẹ̀rẹ̀ títún ilé rẹ̀ kọ́. Carmen sọ pé: “Jèhófà kì í gbàgbé wa, ó sì máa ń tọ́jú wa. Ẹ wo ilé rèǹtèrente táwọn ará ń kọ́ fún mi. Àwọn aládùúgbò mi sọ fún mi pé: ‘Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń tọ́jú àwọn ará wọn; ìfẹ́ tòótọ́ ni wọ́n ní síra wọn.’” Bí àwọn tó ń ṣèrànwọ́ ṣe ń ran àwọn ará wa tí àjálù yìí hàn léèmọ̀ lọ́wọ́ jákèjádò orílẹ̀-èdè náà ni wọ́n ń gbọ́ irú ọ̀rọ̀ ìmoore yìí.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjì líle tí wọ́n pè ní Georges fa àjálù tí kò mọ níwọ̀n, bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe fìfẹ́ pèsè ìrànwọ́ mú ìtura nípa tara àti nípa tẹ̀mí bá àwọn ará wa tí ìjì náà ṣe lọ́ṣẹ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, bí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ara wọn fún iṣẹ́ yìí mú ìyìn bá orúkọ Jèhófà tó máa ń tù wá nínú ní gbogbo ìgbà.

A Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba Púpọ̀ Sí I

Bí iye àwọn tó ń di ọmọ ẹ̀yìn ṣe ń yára pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ là ń nílò Gbọ̀ngàn Ìjọba púpọ̀ sí i. Torí náà, ní oṣù November ọdún 2000, àwọn ará tó wà ní Orílẹ̀-èdè Dominican bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n jàǹfààní ètò tó wà fún àwọn ilẹ̀ táwọn ará ò ti fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́. Èyí mú kó ṣeé ṣe fún àwọn ìjọ láti fi nǹkan bí ọ̀sẹ̀ mẹ́jọ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó dára tó sì bójú mu. Nígbà tó fi máa di oṣù September ọdún 2011, ó tó Gbọ̀ngàn Ìjọba márùndínláàádọ́jọ [145] tí méjì lára àwùjọ tó ń kọ́lé ti kọ́ tàbí tí wọ́n tún ṣe.

Àwọn ilé yìí àtàwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ ọ máa ń ní ipa pàtàkì lórí àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará rí ilẹ̀ kan tó ṣeé fi kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní ìlú kékeré kan lápá àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan béèrè lọ́wọ́ ẹni tó ni ilẹ̀ yìí bóyá ó fẹ́ tà á. Onílẹ̀ náà fèsì pé: “O jẹ́ má fàkókò ẹ ṣòfò, tó bá jẹ́ pé ṣọ́ọ̀ṣì lo fẹ́ kọ́ sórí ilẹ̀ yìí, mi ò ní tà á fún ẹ.”

Kò pẹ́ rárá lẹ́yìn náà tí ẹni tó fẹ́ ta ilẹ̀ yìí lọ kí ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Puerto Plata. Nígbà tó débẹ̀, ó rí i pé ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ti gbé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń ṣàìsàn lọ sílé wọn, wọ́n sì ń tọ́jú rẹ̀ níbẹ̀. Ìdílé náà gbé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yìí lọ sọ́dọ̀ dókítà, wọ́n sì tún máa ń gbé e lọ sípàdé àti òde ẹ̀rí. Ọkùnrin náà bi ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé èló ló san fún gbogbo ìtọ́jú tí wọ́n fún un yìí. Ó fèsì pé: “Mi ò sanwó rárá. Arákùnrin mi ni wọ́n.”

“Mi ò tíì ráwọn èèyàn tí wọ́n wà níṣọ̀kan, tí wọ́n sì láàánú báyìí rí”

Inú rere tó ṣàrà ọ̀tọ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí fi hàn yìí wú onílẹ̀ náà lórí débi pé ó pe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó wá bá a tẹ́lẹ̀ pé òun ti yí èrò òun pa dà, òun sì ti ṣe tán láti ta ilẹ̀ náà. Àwọn ará ra ilẹ̀ náà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sórí rẹ̀. Ìyàwó ẹni tó ni ilẹ̀ náà kò fẹ́ràn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ́lẹ̀. Àmọ́ nígbà tó rí bí àwọn ará ṣe kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìkọ́lé náà, ó sọ pé, “Mi ò tíì ráwọn èèyàn tí wọ́n wà níṣọ̀kan, tí wọ́n sì láàánú báyìí rí.”