Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Imititi Ile Lorile-Ede Haiti

Imititi Ile Lorile-Ede Haiti

Ìbísí Láwọn Ibi Tí Wọ́n Ti Ń Sọ Èdè Chinese

Ní ọdún 2005, ẹ̀ka ọ́fíìsì rán Arákùnrin Tin Wa Ng tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, tó sì ń sọ èdè Chinese, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe pé kó lọ máa wàásù fún àwọn tó ń sọ èdè náà ní Orílẹ̀-èdè Dominican. Orílẹ̀-èdè Dominican ni wọ́n ti bí i, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti tọ́ ọ dàgbà. Láti ilẹ̀ Ṣáínà làwọn òbí rẹ̀ ti kó wá sílùú Santo Domingo.

Wọ́n dá ìjọ tó ń sọ èdè Mandarin Chinese sílẹ̀ ní January 1, ọdún 2008 nílùú Santo Domingo, wọ́n sì dá àwùjọ kan sílẹ̀ nílùú Santiago lọ́dún 2011. Àwọn akéde, aṣáájú-ọ̀nà déédéé mẹ́rìndínlógójì [36] àti àwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ mélòó kan tí gbogbo wọn jẹ́ àádọ́rin [70] nínú ìjọ àti àwùjọ yìí, ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó tó mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] lóṣooṣù.

A Wá Àwọn Tó Ń Sọ Èdè Gẹ̀ẹ́sì Kàn

Ní ọdún 2007, iye akéde ti di ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n, irínwó àti mẹ́rìndínláàádọ́rin [27,466], iye ìjọ jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [376], iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínláàádọ́ta, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin àti márùndínlọ́gọ́rùn-ún [49,795]. Àmọ́, kò sí ìjọ kankan tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì, àwọn èèyàn tó ń sọ èdè náà sì pọ̀. Torí náà, ní oṣù April ọdún 2008, ẹ̀ka ọ́fíìsì rán Donald àti Jayne Elwell tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì lọ sí ìlú Santo Domingo pé kí wọ́n lọ dá àwùjọ tí yóò máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì sílẹ̀ níbẹ̀. Àwọn akéde mélòó kan tí wọ́n nítara ti kọ́kọ́ wádìí láti mọ àwọn ibi táwọn tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì wà. Wọ́n wá ṣètò ìpínlẹ̀ ìwàásù náà kí wọ́n lè jẹ́rìí kúnnákúnná fún wọn.

Gbogbo akitiyan yìí mú kí àwùjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì nílùú Santo Domingo túbọ̀ máa gbèrú. Àwùjọ ọ̀hún wá di ìjọ lóṣù July ọdún 2009, akéde mọ́kàndínlógójì [39] ló sì wà níbẹ̀. Wọ́n ṣe ohun kan náà láwọn apá ibòmíì lórílẹ̀-èdè náà. Nígbà tó sì fi máa di oṣù November ọdún 2011, ìjọ méje àti àwùjọ kan tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì ló ti wà lórílẹ̀-èdè náà.

Obìnrin Adití Kan Tí Ojú Rẹ̀ Fọ́ Pinnu Láti Sin Jèhófà

Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan ń fọwọ́ ṣàpèjúwe sínú ọwọ́ Lorys láti bá a sọ̀rọ̀

Ìgbà tí obìnrin kan tó ń jẹ́ Lorys wà ní kékeré làwọn òbí rẹ̀ ti ṣaláìsí. Àìsàn kan tó ṣe é mú kó ya adití látìgbà tí wọ́n ti bí i, ojú rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í di bàìbàì, ó sì fọ́ nígbà tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún [16]. Ó máa ń ríran díẹ̀díẹ̀ lójú mọmọ, àmọ́ kì í ríran rárá tí ilẹ̀ bá ti ṣú. Tó bá fẹ́ bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ lálẹ́, àfi kó fọwọ́ ṣàpèjúwe sínú ọwọ́ onítọ̀hún.

Tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe rí Lorys nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlélógún [23]. Ó ń gbé pẹ̀lú ọkùnrin adití kan nígbà yẹn, ọmọbìnrin wọn tí kò yadi sì ti pé ọmọ ọdún kan. Nígbà tí wọ́n pe Lorys wá sípàdé, ó lọ, ohun tó kọ́ níbẹ̀ sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an.

Obìnrin tó ń jẹ́ Lorys yìí yára ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé kò bójú mu láti máa gbé pẹ̀lú ọkùnrin láìjẹ́ pé wọ́n ṣègbéyàwó, ó ṣàlàyé fún ọkùnrin tí wọ́n jọ ń gbé nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn ṣègbéyàwó lọ́nà tó bófin mu, ó sì sọ fún un pé ìlànà íbélì nípa ìwà híhù lòun fẹ́ tẹ̀ lé. Bí Lorys ṣe fìgboyà sọ̀rọ̀ yìí ya ọkùnrin náà lẹ́nu, ó sì gbà pé kí wọ́n jọ ṣègbéyàwó.

Lẹ́yìn tí wọ́n ṣègbéyàwó, Lorys di akéde, kò sì pẹ́ lẹ́yìn náà ló ṣèrìbọmi. Nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó kọ́ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà. Látìgbà náà wá ló sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà.

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Tó Runlérùnnà Wáyé Lórílẹ̀-Èdè Haiti

Ọjọ́ mánigbàgbé ni Tuesday, January 12, ọdún 2010 jẹ́ fáwọn ọmọ ilẹ̀ Dominican àti Haiti. Ọjọ́ yẹn ni ìmìtìtì ilẹ̀ tó runlérùnnà wáyé lórílẹ̀-èdè Haiti. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fún ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Orílẹ̀-èdè Dominican láṣẹ pé kí wọ́n fowó ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti orílẹ̀-èdè Haiti láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí pé owó tí wọ́n fẹ́ fi ránṣẹ́ náà pọ̀ díẹ̀, Arákùnrin Evan Batista, tó rí fìrìgbọ̀n tó sì jẹ́ dókítà ní Bẹ́tẹ́lì ni wọ́n rán pé kó gbé owó náà lọ fún wọn.

Àǹfààní wà nínú bí wọ́n ṣe pinnu láti rán Arákùnrin Batista lọ, torí pé nígbà tó dé ẹnubodè, wọ́n sọ fún un pé wọ́n nílò àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ onímọ̀ ìṣègùn lójú méjèèjì. Ọ̀pọ̀ àwọn tó fara pa yánnayànna nígbà ìmìtìtì ilẹ̀ náà ni wọ́n gbé wá sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Haiti láti wá gbàtọ́jú. Nígbà tí àwọn ará lórílẹ̀-èdè Haiti rí i pé dókítà ni Arákùnrin Batista, wọ́n pe ẹ̀ka ọ́fíìsì Orílẹ̀-èdè Dominican láti béèrè bóyá arákùnrin náà lè dúró ní Haiti láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ̀ka ọ́fíìsì gbà pé kó dúró, bó ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àṣekára láti ran àwọn arákùnrin wa lọ́wọ́ lórílẹ̀-èdè Haiti nìyẹn. Gbogbo èyí ò ju wákàtí mélòó kan péré lẹ́yìn tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà wáyé.

Àwọn ará dìde ìrànwọ́ lẹ́yìn ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé lọ́dún 2010 lórílẹ̀-èdè Haiti

Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ẹ̀ka Ìrajà ní ọ́fíìsì wa ní Orílẹ̀-èdè Dominican ti pe àwọn tí wọ́n ń ra oúnjẹ lọ́wọ́ wọn pé kí wọ́n gbé oúnjẹ wá. Torí náà, a ra àpò ìrẹsì àti àpò ẹ̀wà tó tó mẹ́rìndínlógóje [136] àti onírúurú oúnjẹ míì, a sì kó wọn ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè Haiti ní aago méjì ààbọ̀ òru ọjọ́ Thursday, January 14. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹrù yìí ló kọ́kọ́ dé ẹnubodè Orílẹ̀-èdè Haiti lára àwọn ẹrù ìrànwọ́ tó wá láti orílẹ̀-èdè míì. Lọ́jọ́ yẹn kan náà, dókítà mẹ́ta míì láti Orílẹ̀-èdè Dominican rin ìrìn wákàtí méje wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Haiti. Ilẹ̀ ti ṣú kí wọ́n tó dé, àmọ́ dípò kí wọ́n lọ sí ibi tí wọ́n dé sí, ọ̀dọ̀ àwọn tó fara pa ni wọ́n gbà lọ, ibẹ̀ ni wọ́n sì wà títí di ọ̀gànjọ́. Lọ́jọ́ kejì, dókítà mẹ́rin míì àti nọ́ọ̀sì mẹ́rin tún ti dé láti Orílẹ̀-èdè Dominican. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo yàrá kan ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà láti ṣe iṣẹ́ abẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn rárá láti ṣe iṣẹ́ náà níbẹ̀. Nígbà tí àwọn méjìlá yìí fi máa lo ọ̀sẹ̀ kan, wọ́n ti tọ́jú èèyàn tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] lára àwọn tó fara pa.

Ojoojúmọ́ la máa ń gbé àwọn tí a kò bá lè tọ́jú níbẹ̀ torí bí wọ́n ṣe fara pa tó lọ sí Orílẹ̀-èdè Dominican láti lọ gbàtọ́jú. Nígbà míì, ọkọ̀ tí wọ́n bá fi kó ẹrù tí wọ́n fi ṣèrànwọ́ wá sí Haiti ló máa ń yára kó àwọn tó fara pa yìí lọ sáwọn ilé ìwòsàn káàkiri Orílẹ̀-èdè Dominican. Ẹ̀ka ọ́fíìsì ṣètò Ẹgbẹ́ Tó Ń Bẹ Àwọn Aláìsàn Wò láti fún àwọn tó fara pa níṣìírí, kí wọ́n sì rí i dájú pé wọ́n ń rí oògùn àtàwọn ohun tí wọ́n nílò gbà. Àwọn ìjọ ní Orílẹ̀-èdè Dominican ń ṣètò oúnjẹ àti ibùgbé fún àwọn mọ̀lẹ́bí tó tẹ̀ lé àwọn èèyàn wọn tó fara pa wá.

Ẹrù rẹpẹtẹ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ṣètọrẹ títí kan oúnjẹ tí ó tó ogún ọ̀kẹ́ èèyàn jẹ

Gbogbo akitiyan táwọn èèyàn Jèhófà ṣe tinútinú lẹ́yìn àjálù yìí túbọ̀ tẹ ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ nínú Òwe 17:17 mọ́ wa lọ́kàn pé: “Alábàákẹ́gbẹ́ tòótọ́ a máa nífẹ̀ẹ́ ẹni ní gbogbo ìgbà, ó sì jẹ́ arákùnrin tí a bí fún ìgbà tí wàhálà bá wà.” Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìrírí ti jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe tipasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀ àti ẹgbẹ́ ará Kristẹni bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀ adúróṣinṣin lójú ikú pàápàá. Ọ̀pọ̀ oṣù ni wọ́n fi ṣiṣẹ́ takuntakun láti pèsè ìrànwọ́. Ẹrù rẹpẹtẹ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ṣètọrẹ títí kan oúnjẹ tí ó tó ogún ọ̀kẹ́ [400,000] èèyàn jẹ. Àwọn ará méjìdínlọ́gọ́rin [78] lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n jẹ́ onímọ̀ ìṣègùn ló wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yíká ayé, àwọn àti ọ̀pọ̀ àwọn tó yọ̀ọ̀da ara wọn sì lo àkókò wọn àti ìmọ̀ iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe láti fi ṣèrànwọ́. *

^ ìpínrọ̀ 1 Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, lọ wo Jí! [Gẹ̀ẹ́sì] December 2010 ojú ìwé 14 sí 19.