Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Àrùn Kòrónà Ti Pa Mílíọ̀nù Mẹ́fà Èèyàn​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Àrùn Kòrónà Ti Pa Mílíọ̀nù Mẹ́fà Èèyàn​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Àjọ Ìlera Àgbáyé (ìyẹn WHO) sọ pé títí di May 23, 2022, ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́fà àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (6.27 million) ni àrùn Kòrónà ti pa. Àmọ́ nínú ìròyìn kan tó jáde ní May 5, 2022, Àjọ Ìlera Àgbáyé sọ pé ó ṣeé ṣe kí iye àwọn tí àrùn náà ti pa jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àjọ náà sọ pé láàárín ọdún 2020 sí 2021, “iye àwọn tí àrùn náà pa ní tààràtà tàbí tó kú látàrí àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ àjàkálẹ̀ àrùn náà máa fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (14.9 million).” Kí ni Bíbélì sọ nípa irú àwọn àjálù tó ń bani lọ́kàn jẹ́ bẹ́ẹ̀?

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àjàkálẹ̀ àrùn tó burú gan-an á máa ṣẹlẹ̀

  •    Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé “àjàkálẹ̀ àrùn” á máa ṣẹlẹ̀ lásìkò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”​—Lúùkù 21:11, Bíbélì Mímọ́; 2 Tímótì 3:1.

 Ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ yẹn ti ń ṣẹ lónìí. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Àmì Wo Ló Fi Hàn Pé A Ti Wà Ní ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,’ Tàbí ‘Òpin Ayé’?

Bíbélì lè tù wá nínú

  •    “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo . . . ń tù wá nínú nínú gbogbo àdánwò wa.”​—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

 Ọ̀pọ̀ àwọn téèyàn wọn ti kú ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ti tù nínú. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, ka àwọn àpilẹ̀kọ náà “Ohun Tó Lè Ran Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀ Lọ́wọ́“ àti “Ìrànlọ́wọ́ Tó Dára Jù Lọ fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀.“

Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó máa yanjú ìṣòro náà pátápátá

  •    “Kí Ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ ní ayé, bíi ti ọ̀run.”​—Mátíù 6:10.

 Láìpẹ́ “Ìjọba Ọlọ́run” máa rí i pé “kò sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀ tó máa sọ pé: ‘Ara mi ò yá.’” (Máàkù 1:14, 15; Àìsáyà 33:24) Tó o bá fẹ́ mọ̀ nípa ìjọba yìí àtohun tó máa ṣe, wo fídíò náà Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

 A rọ̀ ẹ́ pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n àtàwọn ìlérí tó ń múnú ẹni dùn tó wà nínú ẹ̀ lè ṣe ìwọ àti ìdílé ẹ láǹfààní.