Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Àpéjọ Agbègbè Lórí Tẹlifíṣọ̀n àti Rédíò

Àpéjọ Agbègbè Lórí Tẹlifíṣọ̀n àti Rédíò

AUGUST 1, 2021

 Mánigbàgbé ni àpéjọ agbègbè tá a ṣe lọ́dún 2020. Ìdí ni pé ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tá a máa gba àpéjọ kan sílẹ̀, tá a sì máa gbé e sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kí gbogbo èèyàn lè rí i wò kárí ayé! Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Màláwì àti Mòsáńbíìkì ni wọ́n gbádùn àpéjọ náà láìlo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Báwo ni wọ́n ṣe ṣe é?

 Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí àti Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n gbé àpéjọ agbègbè náà sórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò lórílẹ̀-èdè Màláwì àti Mòsáńbíìkì. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe irú àkànṣe ètò bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Màláwì ni ò lè lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, torí pé owó dátà wọ́n gan-an lórílẹ̀-èdè wọn. Arákùnrin William Chumbi, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Màláwì sọ pé: “Orí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n nìkan ni àwọn ará wa yìí ti lè gbádùn àpéjọ náà.” Arákùnrin Luka Sibeko tóun náà wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka lórílẹ̀-èdè Màláwì sọ pé: “Ká sọ pé a ò rí àpéjọ náà gbé sórí tẹlifísọ̀n àti rédíò ni, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ará tó wà lórílẹ̀-èdè wa ni ò ní láǹfààní láti gbádùn àpéjọ agbègbè náà.” Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì, díẹ̀ nínú àwọn ará tó wà níbẹ̀ ló ní ẹ̀rọ ìgbàlódé láti fi wo àpéjọ náà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ètò Tá A Ṣe

 Nítorí àrùn Corona, a ṣètò pé kí àwọn ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n àti rédíò kan máa gbé àwọn ìpádé ìjọ sáfẹ́fẹ́. a Nígbà tá a fẹ́ ṣe ìpàdé agbègbè, a tún lọ bá àwọn ilé iṣẹ́ yìí kí wọ́n lè bá wa gbé àpéjọ náà sáfẹ́fẹ́.

 Àwọn ará wa ní Màláwì kojú ìṣoro kan. Àwọn ilé iṣẹ́ rédíò àti tẹlifíṣọ̀n tó wà níbẹ̀ kì í jẹ́ kí ètò kọ̀ọ̀kan lò kọjá wákàtí kan lórí afẹ́fẹ́. Àwọn tó ni ilé iṣẹ́ náà sọ pé àwon èèyàn lè má pọkàn pọ̀ mọ́ tí ètò kan bá ti gùn jù. Ṣùgbọ́n àwọn ará wa sọ fún wọn pé ohun tá a fẹ́ ṣe yìí máa ran àwọn ará ìlú lọ́wọ́. Kódà lásìkò kónílégbélé, à ń jẹ́ kí àwọn ará ìlù gbọ́ ìròyìn ayọ̀ látinú Bíbélì, èyí sì ń jẹ́ káwọn èèyàn máa hùwà tó dáa kí ìdílé wọn sì láyọ̀. Nígbà táwọn ilé iṣẹ́ náà gbọ́ ohun táwọn arákùnrin wa sọ yìí, wọ́n gbà láti jẹ́ kí wọ́n lo iye wákàtí tí wọ́n fẹ́ lò.

 Ní Màláwì, ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan àti ilé iṣẹ́ rédíò kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn máa ń tẹ́tí sí jákèjádo orílẹ̀-èdè náà gbé àpéjọ agbègbè sáfẹ́fẹ́. Ní Mòsáńbíìkì, ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan àti ilé iṣẹ́ rédíò márùndínláàádọ́rùn-ún (85) ló gbé àpéjọ náà sáfẹ́fẹ́.

 Dọ́là 28,227 b la ná láti gbé àpéjọ náà sórí tẹlifíṣọ̀n lórílẹ̀-èdè méjèèjì, a sì fẹ́rẹ̀ẹ́ ná tó dọ́là 20,000 láti gbé e sórí rédíò. Àwọn ilé iṣẹ́ rédíò kéékèèké gba nǹkan bíi dólà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15), nígbà táwọn ilé iṣẹ́ rédíò ńlá gbà tó dọ́là 2,777.

 Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn ará wa ṣe láti rí i pé àwọn ṣọ́wó ná. Bí àpẹẹrẹ ní Màláwì, wọ́n dúnàádúrà pẹ̀lú àwọn ilé iṣẹ́ náà débi tí wọ́n fi dín owó tí wọ́n fẹ́ gbà kù. Kódà níbi kan, ohun tó lé ní ìdá kan nínú mẹ́rin ni ilé iṣẹ́ náà yọ kúrò nínú owó tó yẹ ká san. Ohun táwọn ará wa ṣe yìí mú kí dọ́là 1,711 ṣẹ́ kù nínú ohun tá a ronú pé a máa ná. Ní Mòsáńbíìkì, àwọn ilé iṣẹ́ náà dín owó tí wọ́n fẹ́ gbà kù torí wọ́n mọ̀ pé a jẹ́ olóòótọ́, a sì máa ń sanwó lásìkò.

Àwọn Ará Mọrírì Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ṣe

 Inú àwọn ará dùn gan-an láti wo ètò náà lórí tẹlifíṣọ̀n kí wọ́n sì gbọ́ ọ lórí rédíò. Alàgbà kan tó ń jẹ́ Patrick lórílẹ̀-èdè Màláwì sọ pé: “A dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ ìgbìmọ̀ olùdarí fún bí wọ́n ṣe gba tiwa rò lásìkò àrùn Corona yìí.” Isaac tóun náà wá láti Màláwì sọ pé: “A dúpẹ́ pé ètò Ọlọ́run gbé àpéjọ náà sórí rédíò, tí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni, a ò bá má wo àpéjọ yẹn, torí pé rédíò nìkan la ní. Ètò yìí ló mú kó ṣeé ṣe fún èmi àti ìdílé mi láti gbádùn àpéjọ náà. Ohun tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ ká rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.”

 Àpéjọ agbègbè 2020 ni ìgbà àkọ́kọ́ tí akéde kan máa dara pọ̀ mọ́ àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Akéde náà sọ pé: “Ètò tí wọ́n ṣe ká lè wo àpéjọ náà lórí tẹlifíṣọ̀n jẹ́ kó dá mi lójú pé kò sóhun tí Jèhófà ò lè ṣe. Àjàkálẹ̀ àrùn yìí ò dí i lọ́wọ́ láti pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún wa, kódà ó gbé e wá sínú yàrá mi. Mo rí i pé àwọn èèyàn Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wọn, èyí sì mú kí n gbà pé ìsìn tòótọ́ rèé.”

 Alàgbà kan tó ń jẹ́ Wyson sọ pé: “Mo fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹrú olóòótọ́ fún bí wọ́n ṣe bójú tó wa lásìkò Corona yìí. Bí wọ́n ṣe gbé àpéjọ náà sórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n ṣe wá láǹfààní gan-an. Ó ti jẹ́ káwa tá à ń gbé níbi tí nǹkan ò ti rọ̀ṣọ̀mù gbádùn àpéjọ náà.”

 Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí àti Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún ti fọwọ́ sí i pé kí wọ́n gbé àpéjọ agbègbè ti ọdún 2021 sórí rédíò àti tẹlifíṣọ̀n láwọn agbègbè kan. Ibo la ti rí gbogbo owó tá a fi ń ṣiṣẹ́ yìí? Ìtìlẹyìn táwọn ará wa ń ṣe kárí ayé ló jẹ́ ká rí owó yìí. Ọ̀pọ̀ lára ẹ̀ ló jẹ́ pé orí ìkànnì donate.dan124.com ní wọ́n ti fi ránṣẹ́. Ẹ ṣeun ẹ̀yin ará wa fún ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yìn.

a Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2020, Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa gbé àwọn ìpàdé ìjọ sórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò láwọn ilẹ̀ kan nítorí àrùn Corona. Èyí ti jẹ́ káwọn tó ń gbé níbi tí íntánẹ́ẹ̀tì ò ti dáa tàbí tó wọ́n lè gbádùn àwọn ìpàdé náà. Síbẹ̀, ètò yìí ò sí fún àwọn ìjọ tó wà ládùúgbò tí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti dáa.

b Dọ́là owó Amẹ́ríkà la ní lọ́kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí.