Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Ìwé Tó Ń Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní

Ìwé Tó Ń Ṣe Àwọn Èèyàn Láǹfààní

OCTOBER 1, 2021

 Ilé Ìṣọ́ June 1, 1912 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń kàwé wa ló ṣeé ṣe kí wọ́n mọ àwọn afọ́jú dáadáa. Àwọn afọ́jú lè gba ìwé wa lọ́fẹ̀ẹ́ . . . . Wọ́n ṣe àwọn álífábẹ́ẹ̀tì tó wà nínú ìwé náà lọ́nà táá fi rọrùn fún wọn láti kà.” Ilé Ìṣọ́ yẹn tún sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn afọ́jú ni inú wọn máa ń dùn láti mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.”

 Nígbà tí Ilé Ìṣọ́ yẹn jáde, kò tíì sí ọ̀nà ìkọ̀wé àwọn afọ́jú tó jẹ́ àjùmọ̀lò irú èyí tá a ní lónìí. Síbẹ̀, ọjọ́ pẹ́ táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìwé àwọn afọ́jú lọ́nà táá mú kó rọrùn fáwọn afọ́jú láti ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ títí dòní! Ní báyìí, à ń tẹ ìwé àwọn afọ́jú ní èdè tó lé ní àádọ́ta (50). Báwo la ṣe ń ṣe é?

Àwọn àmì tó dúró fún álífábẹ́ẹ̀tì táwọn afọ́jú máa ń kà. Wọ́n sì máa ń to mẹ́fà sórí ìlà kan

A Máa Ń Tún Àwọn Ọ̀rọ̀ Náà Kọ Àá Sì Tẹ̀ ẹ́ Sórí Ìwé

 Ohun àkọ́kọ́ tá a máa ń ṣe tá a bá fẹ́ tẹ ìwé àwọn afọ́jú ni pé, àá sọ àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé náà di èyí táwọn afọ́jú lè kà. Arákùnrin Michael Millen tó ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń To Ọ̀rọ̀ Pọ̀ ní Patterson, New York sọ pé: “Láwọn ìgbà kan, a máa ń lo ètò ìṣiṣẹ́ táwọn míì ṣe, àmọ́ kì í ṣe gbogbo èdè tá a fẹ́ tú ìwé àwọn afọ́jú sí ló wà nínú ètò ìṣiṣẹ́ náà. Ṣùgbọ́n ní báyìí, a ti ń lo Watchtower Translation System, torí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo èdè tó wà láyé ló wà nínú ẹ̀. Ètò ìṣiṣẹ́ yìí dáa gan-an, kò sírú ẹ̀ níbòmíì.”

 Kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé nìkan ló wà nínú ìwé àwọn afọ́jú, ó tún ní àlàyé nípa àwọn àwòrán tó wà nínú ìwé náà. Bí àpẹẹrẹ, bá a ṣe ṣàlàyé àwòrán tó wà níwájú ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! rèé: “Ọkùnrin kan ń rìn gba ọ̀nà tóóró, àwọn ewéko tó rẹwà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, àwọn òkè sì wà nítòsí.” Jamshed tó jẹ́ ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti aṣáájú ọ̀nà, àmọ́ tó jẹ́ afọ́jú sọ pé, “Mo mọyì bí wọ́n ṣe ṣàlàyé àwọn àwòrán yẹn gan-an.”

 Lẹ́yìn tá a bá ti yí àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé náà pa dà, a máa ń fi ránṣẹ́ sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì tó máa ń tẹ iwé àwọn afọ́jú. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń tẹ álífábẹ́ẹ̀tì táwọn afọ́jú lè kà sórí ìwé tó nípọn, tí ò ní ya tí wọ́n bá ń tẹ ọ̀rọ̀ sórí ẹ̀, táwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ò sì ní parẹ́ tó bá yá. Lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n máa kó àwọn ìwé náà pọ̀, wọ́n á dì í, wọ́n á sì fi wọ́n ránṣẹ́ sáwọn ìjọ tàbí kí wọ́n kọ “ìwé àwọn afọ́jú” sára ẹ̀ kí wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí ilé ìfìwéránṣẹ́. Nígbà míì sì rèé, ẹ̀ka ọ́fíìsì lè ṣètò pé kí wọ́n tètè fi àwọn ìwé náà ránṣẹ́ káwọn ará tó jẹ́ afọ́jú àtàwọn tí ò ríran dáadáa lè rí ìtẹ̀jáde lò fún ìpàdé.

 Iṣẹ́ yìí máa ń gba àkókò, ó sì máa ń ná wa lówó gan-an. Kódà, nílé ìtẹ̀wé wa ní Wallkill New York, iye àkókò tá a máa ń lò láti ṣe Bíbélì àwọn afọ́jú méjì péré náà la máa ń lò láti tẹ Bíbélì tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000). Bíbélì kọ̀ọ̀kan táwọn afọ́jú ń lò ní ìdìpọ̀ márùndínlọ́gbọ̀n (25), iye tá a máa ń ná láti ṣe gbogbo ìdìpọ̀ yìí máa tó láti tẹ Bíbélì ọgọ́rùn-ún kan àti mẹ́tàlélógún (123). Kódà ẹ̀yìn ìwé gbogbo ìdìpọ̀ yẹn nìkan máa ń ná wa ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan àti àádọ́ta (150) owó dọ́là!

Ìdìpọ̀ márùndínlọ́gbọ̀n (25) ló para pọ̀ di Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè àwọn afọ́jú!

 Báwo niṣẹ́ yìí ṣe rí lára àwọn tó ń tẹ ìwé àwọn afọ́jú? Arábìnrin Nadia tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì South Africa sọ pé: “Nǹkan ò rọrùn rárá fáwọn ará wa tó jẹ́ afọ́jú àtàwọn tí ò ríran dáadáa, torí náà àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ló jẹ́ fún mi láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Ó jẹ́ kí n túbọ̀ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn gan-an.”

Ìwé Learn to Read Braille

 Àmọ́, tí afọ́jú kan ò bá lè ka ìwé àwọn afọ́jú ńkọ́? Láwọn ọdún díẹ̀ sẹ́yìn, a ṣe ìwé kan tá a pè ní Learn to Read Braille. Ìwé àwọn afọ́jú ni, àmọ́ ó tún ní àwọn ọ̀rọ̀ míì níbẹ̀. A ṣe é lọ́nà tó fi jẹ́ pé ẹni tó ríran àtẹni tó fọ́jú lè kà á. Yàtọ̀ sí ìwé yẹn, a tún ṣe ẹ̀rọ kan táwọn afọ́jú lè fi kọ̀wé. Àwọn afọ́jú tí ò mọ̀wé kà máa ń lo ìwé àti ẹ̀rọ yìí láti fi kọ ọ̀rọ̀ fúnra wọn. Ìyẹn máa ń jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti rántí àwọn ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì lè fi ọwọ́ dá ọ̀rọ̀ mọ̀.

“Mi Ò Lè Ṣe Kí N Má Kà Wọ́n”

 Báwo làwọn ìtẹ̀jáde yìí ṣe ran àwọn ará wa tó jẹ́ afọ́jú àtàwọn tí ò ríran dáadáa lọ́wọ́? Arákùnrin Ernst tó ń gbé ní Haiti máa ń lọ sípàdé, àmọ́ kò ní ìwé àwọn afọ́jú kankan lọ́wọ́. Torí náà, tó bá níṣẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ tàbí tó fẹ́ dáhùn nípàdé, ṣe ló máa ń há gbogbo ohun tó fẹ́ sọ sórí. Ó wá sọ pé: “Ní báyìí, mo lè nawọ́ nígbà tó bá wù mí láti dáhùn nípàdé. Inú mi dùn pé mo wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ẹgbẹ́ ará kárí ayé torí pé oúnjẹ tẹ̀mí kan náà la jọ ń jẹ!”

 Alàgbà kan tó ń jẹ́ Jan tó ń gbé ní Austria ò ríran dáadáa, òun ló sì ń darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ. Ó sọ pé: “Ìtẹ̀jáde àwọn afọ́jú tí ètò Ọlọ́run ṣe rọrùn láti lóye ju ìwé àwọn afọ́jú míì lọ. Bí àpẹẹrẹ, ó rọrùn gan-an láti rí nọ́ńbà ojú ìwé àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, àlàyé tí wọ́n sì máa ń ṣe nípa àwọn àwòrán ṣe kedere.”

 Afọ́jú ni arábìnrin aṣáájú-ọ̀nà kan tó ń jẹ́ Seon-ok tó ń gbé ní South Korea, yàtọ̀ síyẹn adití ni. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ẹnì kan ló máa ń fọwọ́ ṣàpèjúwe fún arábìnrin yìí nípàdé, àmọ́ ó ti lè ka ìwé àwọn afọ́jú fúnra ẹ̀ báyìí. Ó sọ pé: “Ìwé àwọn afọ́jú míì máa ń ṣòro kà torí pé ó lè má ní àmì, kí ìlà ẹ̀ wọ́, tàbí kí bébà tí wọ́n fi tẹ̀ ẹ́ fẹ́lẹ́ jù. Àmọ́ ètò Ọlọ́run máa ń fi bébà tó dáa ṣe ìwé àwọn afọ́jú, wọ́n sì máa ń tẹ àwọn ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tí àmì ẹ̀ fi máa hàn dáadáa, ìyẹn sì ti jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti kà.” Ó wá fi kún un pé: “Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, mi ò lè dá ka àwọn ìwé wa láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn míì. Àmọ́ mo ti lè dá kàwé báyìí. Inú mi dùn pé mo lè múra àwọn ìpàdé sílẹ̀, mo sì lè dáhùn nípàdé. Ní báyìí, kò sí ìwé àwọn afọ́jú tí mi ò lè kà. Kódà mo lè sọ pé mi ò lè ṣe kí n má kà wọ́n.”

 Bíi tàwọn ìtẹ̀jáde wa tó kù, ìwé àwọn afọ́jú náà ní àwọn ọ̀rọ̀ yìí: “Ìtẹ̀jáde yìí kì í ṣe títà. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń fi ọrẹ àtinúwá tì lẹ́yìn.” Ẹ ṣeun gan-an fáwọn ìtìlẹyìn tẹ́ ẹ̀ ń fi ránṣẹ́ nípasẹ̀ ìkànnì donate.dan124.com. Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín ló ń mú ká lè máa ṣe àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣe gbogbo èèyàn láǹfààní títí kan àwọn afọ́jú àtàwọn tí ò ríran dáadáa.