Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iyẹ̀pẹ̀ tó ju tọ́ọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) la kó lọ sí Mt. Ebo nígbà tá a fẹ́ ṣe fídíò yìí

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

A Ṣe Àwọn Fídíò Tá A Wò ní Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti Ọdún 2020

A Ṣe Àwọn Fídíò Tá A Wò ní Àpéjọ Agbègbè “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti Ọdún 2020

AUGUST 10, 2020

 Àwọn fídíò tá a máa ń wò láwọn àpéjọ agbègbè wa máa ń wọ̀ wá lọ́kàn gan-an, ó sì máa ń jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ní àpéjọ agbègbè “Ẹ Máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti Ọdún 2020, a wo fídíò mẹ́rìnléláàádọ́fà (114). Àwọn àsọyé mẹ́tàlélógójì (43) táwọn tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí àtàwọn olùrànlọ́wọ́ wọn sọ sì wà lára àwọn fídíò yìí. Ó ṣeé ṣe kẹ́yìn náà ti máa wò ó pé iṣẹ́ yìí máa ná wa ní ohun tó pọ̀ ká tó lè parí ẹ̀.

 Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án (900) àwọn ará lọ́kùnrin lóbìnrin kárí ayé ló lo àkókò àti òye wọn kí iṣẹ́ yìí lè ṣeé ṣe. Lápapọ̀, gbogbo wọn lo nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000) wákàtí fún ohun tó lé ní ọdún méjì lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Fídíò Nehemáyà: “Ìdùnnú Jèhófà Ni Ibi Ààbò Yín” tó gùn tó ìṣẹ́jú mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (76) wà lára fídíò tí wọ́n ṣe, ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rin (70,000) wákàtí ni wọ́n sì fi ṣe é.

 Bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀, owó kékeré kọ́ la máa ná ká tó lè tọ́jú àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe iṣẹ́ yìí, ká sì tún pèsè àwọn nǹkan tí wọ́n nílò fún iṣẹ́ náà.

 Arákùnrin Jared Gossman, tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń gbohùn sílẹ̀ sọ pé: “Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí fẹ́ ká máa lo onírúurú àṣà nínú àwọn fídíò wa, ká sì máa ṣe é láwọn ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, káwọn ará lè máa rí i pé a wà níṣọ̀kan kárí ayé. Kíyẹn lè ṣeé ṣe, àwùjọ mẹ́rìnlélógún (24) láti orílẹ̀-èdè mọ́kànlá (11) ló para pọ̀ ṣiṣẹ́ lórí àwọn fídíò yìí. Torí pé ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni gbogbo wọn wà, owó kékeré kọ́ la ná ká tó lè ṣètò bí wọ́n ṣe máa ṣiṣẹ́, ká sì tún bójú tó wọn.”

 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn irin iṣẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ la fi ń ṣe ọ̀pọ̀ àwọn fídíò wa, a sì tún máa ń nílò ibi tá a ti máa ṣe wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tá a fẹ́ ṣe fídíò Nehemáyà: “Ìdùnnú Jèhófà Ni Ibi Ààbò Yín,” a ṣe ohun tó jọ ògiri sínú yàrá ìgbohùnsílẹ̀ tó wà ní Mt. Ebo nítòsí Patterson, New York. Ká lè ṣọ́wó ná, ká sì tún rí i pé ó jọ bí nǹkan ṣe rí láyé ìgbà yẹn, wọ́n fi pákó ṣe ògiri lóríṣiríṣi, wọ́n sì fi fóòmù bò ó lárá, èyí mú kó fúyẹ́. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ògiri yẹn ga tó mítà mẹ́fà (nǹkan bíi 20 ft), nígbà tí wọ́n sì kùn ún tán, ó jọ ògiri Jerúsálẹ́mù ayé ìgbà yẹn. Torí pé àwọn “ògiri” yẹn ṣeé tì kiri, a lè tún un tò kó lè jọ ibi tó yàtọ̀ síra, èyí sì mú ká dín iye ògiri tá a ní láti ṣe kù. Síbẹ̀, nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìdínlógójì àtààbọ̀ (38,500,000) náírà la ná ká tó lè ṣe ibi tá a ti ṣe fídíò yẹn. a

 A gbà pé ohun tẹ́ ẹ mọ̀ yìí á jẹ́ kẹ́ ẹ túbọ̀ mọyì àpéjọ agbègbè ọdún yìí. Ó dá wa lójú pé ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn ará wa ṣe ká lè gbádùn àpéjọ yìí máa mú kí gbogbo wa yin Jèhófà kárí ayé. A mọyì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín, a sì dúpẹ́ fún bẹ́ ẹ ṣe ń ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ kárí ayé látorí ìkànnì donate.dan124.com àti láwọn ọ̀nà míì.

a Àrùn Corona ò tíì bẹ̀rẹ̀ nígbà tá à ń ṣe fídíò Nehemáyà: “Ìdùnnú Jèhófà Ni Ibi Ààbò Yín. Torí náà, kò sídìí àti jìnnà síra wa nígbà yẹn.