Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

A Pèsè Ìrànwọ́ Fáwọn Tí Àjálù Ṣẹlẹ̀ Sí

A Pèsè Ìrànwọ́ Fáwọn Tí Àjálù Ṣẹlẹ̀ Sí

FEBRUARY 1, 2021

 Ọ̀pọ̀ àjálù ló ṣẹlẹ̀ lọ́dún 2020, ọdún yẹn kan náà ni àrùn Corona bẹ̀rẹ̀ kárí ayé. Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù yẹn ṣẹlẹ̀ sí?

 Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, a Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí i pé ká ná ohun tó ju bílíọ̀nù mẹ́wàá ààbọ̀ náírà láti ṣèrànwọ́ fáwọn tí àjálù dé bá. Lọ́dún yẹn nìkan, àjálù tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ará wa ju igba (200) lọ, àwọn àjálù bí àrùn Corona, ìjì líle, omíyalé ní Áfíríkà, àìtó oúnjẹ ní Venezuela, àti ọ̀gbẹlẹ̀ ní Zimbabwe. Owó tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí fọwọ́ sí yìí la fi ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa, a pèsè oúnjẹ, omi, ilé, aṣọ, a bójú tó ìlera wọn, a ṣàtúnṣe sáwọn ibi tó bà jẹ́, a sì tún àwọn ilé kan kọ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a ṣe láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa.

 Àrùn Corona. Àrùn yìí ti mú kí nǹkan nira fáwọn ará wa níbi gbogbo kárí ayé, ó ti fa ẹ̀dùn ọkàn fáwọn kan, ó sì ti mú kí ọrọ̀ ajé dẹnu kọlẹ̀ fáwọn míì. Ká lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́, a ṣètò Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ (800) kárí ayé. Àwọn ìgbìmọ̀ yìí máa ń ṣàyẹ̀wò ohun táwọn ará wa nílò, wọ́n á sì fi tó Ìgbìmọ̀ Olùṣekòkáárí létí láìjáfara, kí wọ́n lè mọ ọ̀nà tó dáa jù láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa.

 Jálẹ̀ ọdún 2020 ni ìgbìmọ̀ yìí fi ṣètò báwọn ará wa ṣe máa rí oúnjẹ, omi, oògùn àtàwọn nǹkan tí wọ́n lè fi dènà àrùn. Láwọn ilẹ̀ kan, ìgbìmọ̀ yìí àtàwọn alàgbà bá àwọn ará wa ṣètò bí wọ́n ṣe máa rí ìrànlọ́wọ́ gbà látọ̀dọ̀ ìjọba.

 Àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kíyè sí bá a ṣe ń ran àwọn ará wa lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀gbẹ́ni Field Simwinga, tó jẹ́ kọmíṣọ́nnà lágbègbè Nakonde lórílẹ̀-èdè Zambia sọ fáwọn ará wa pé: “Ìrànlọ́wọ́ tẹ́ ẹ ṣe fáwọn ìdílé tí àjálù dé bá lágbègbè yìí bọ́ sásìkò gan-an, a dúpẹ́ lọ́wọ́ yín.”

 Àìtó Oúnjẹ ní Àǹgólà. Àwọn èèyàn ò rí oúnjẹ tó tó jẹ ní Àǹgólà torí àrùn Corona, ìwọ̀nba oúnjẹ tó wà sì ti gbówó lórí. Ìyẹn mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa láti rí oúnjẹ tó tó jẹ.

Àwọn àpò oúnjẹ tá a fi ránṣẹ́ láti Brazil sí Àǹgólà

 A ní kí ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Brazil fi oúnjẹ ránṣẹ́ sáwọn ará wa tó wà lórílẹ̀-èdè Àǹgólà. Ká lè ṣọ́wó ná, a fara balẹ̀ ṣèwádìí ká lè mọ irú oúnjẹ tá a máa rà àti ọ̀nà tó dáa jù láti fi ránṣẹ́, a sì ra àwọn oúnjẹ náà pa pọ̀. Torí náà, ní ìpíndọ́gba nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ àtààbọ̀ (8,500) náírà péré la ná láti ra àpò oúnjẹ kọ̀ọ̀kan àti láti fi ránṣẹ́. A kó ìrẹsì, ẹ̀wà àti òróró sínú àpò kọ̀ọ̀kan, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ wúwo tó ìlàjì àpò sìmẹ́ǹtì. Ní báyìí, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mẹ́rìnlélógójì (33,544) àpò oúnjẹ la ti fi ránṣẹ́, àpapọ̀ ẹ̀ sì wúwo ju ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá (13,000) àpò sìmẹ́ǹtì. Nígbà tí wọ́n pa oúnjẹ yìí pọ̀ mọ́ èyí táwọn ará fi ṣètìlẹyìn lórílẹ̀-èdè náà, àwọn tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta (50,000) ló jàǹfààní ètò tá a ṣe yìí!

 Báwo ló ṣe rí lára àwọn ará nígbà tí wọ́n rí oúnjẹ náà gbà? Arákùnrin Alexandre tó ń gbé lápá ibì kan tó jìnnà lórílẹ̀-èdè Àǹgólà sọ pé: “Ẹ̀bùn yìí jẹ́ kó dá mi lójú pé Jèhófà ò fi mí sílẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ mi. Ó tún jẹ́ kí n rí i pé ètò Ọlọ́run mọyì mi!” Arábìnrin Mariza, tó jẹ́ òbí tó ń dá tọ́mọ sọ pé: “Jèhófà rí omijé mi, ó sì gbọ́ àdúrà mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà àti ètò rẹ̀!”

Inú àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Àǹgólà dún nígbà tí wọ́n rí oúnjẹ gbà

 Ètò Ìrànwọ́ ní Zimbabwe. Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, ọ̀gbẹlẹ̀ tó lágbára ṣẹlẹ̀ ní Zimbabwe, ìyẹn sì mú kó nira fún ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn láti rí oúnjẹ jẹ. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè yìí ni ò sì rí oúnjẹ tó tó jẹ.

 A ṣètò ìgbìmọ̀ márùn-ún láti pèsè ìrànwọ́ fáwọn ará wa. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará ló ṣèrànwọ́ láti di àwọn oúnjẹ yẹn àti láti kó o sínú mọ́tò, àwọn míì sì yọ̀ǹda mọ́tò wọn kí wọ́n lè fi kó ẹrù náà. b Lọ́dún iṣẹ́ ìsìn 2020, a ná ohun tó lé ní mílíọ̀nù lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́tàlélọ́gọ́ta (263,000,000) náírà láti pèsè oúnjẹ fáwọn tó ju ẹgbẹ̀rún méjìlélógún àti ọgọ́rùn-ún méje (22,700)!

Àwọn ará wa ní Zimbabwe rí oúnjẹ gbà

 Láwọn ibì kan, oúnjẹ àwọn ará wa ti lè tán kóúnjẹ tá a fi ránṣẹ́ tó dé ọ̀dọ̀ wọn. Torí náà, wọ́n máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tí wọ́n bá rí oúnjẹ náà gbà. Àwọn míì tiẹ̀ máa ń kọ orin Ìjọba Ọlọ́run.

 Lágbègbè kan, àwọn arábìnrin méjì tó jẹ́ opó lọ sípàdé tí wọ́n ń ṣe ládùúgbò, kí wọ́n lè gba oúnjẹ tí àjọ kan tí kì í ṣe ti ìjọba (NGO) fẹ́ fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Àmọ́, wọ́n wá rí i pé wọ́n ti ń ti ọ̀rọ̀ òṣèlú bọ ìpàdé náà, làwọn arábìnrin yẹn bá pinnu pé àwọn ò ní lè ṣe ohun tí wọ́n ní káwọn ṣe káwọn tó lè rí oúnjẹ náà gbà. Nígbà tí wọ́n ń kúrò nípàdé náà, ṣe làwọn tó kù ń fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì ń sọ fún wọn pé: “Ẹ má wá tọrọ oúnjẹ lọ́wọ́ wa o!” Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì péré, ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ gbé oúnjẹ dé agbègbè táwọn arábìnrin yìí wà, kí àjọ NGO tó gbé oúnjẹ débẹ̀ rárá!

“Prisca sọ pé: “Jèhófà ò já àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ kulẹ̀ rí”

 Ètò ìrànwọ́ tá a ṣe fáwọn ará wa ní Zimbabwe tún jẹ́ káwọn míì mọ̀ nípa Jèhófà. Àpẹẹrẹ kan ni ti Prisca tó ń gbé ní abúlé kékeré kan. Láìka bí ọ̀gbẹlẹ̀ yẹn ṣe mú kí nǹkan nira tó, Prisca rí i pé òun ń wàásù ní gbogbo ọjọ́ Wednesday àti Friday, kódà lásìkò tó yẹ kó máa ṣètò ilẹ̀ tá gbin nǹkan sí. Torí náà, àwọn ará abúlé bẹ̀rẹ̀ sí í fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Ebi nìwọ àti ìdílé ẹ fi ń ṣeré yìí pẹ̀lú báàgì tó ò ń gbé kiri.” Prisca máa ń dá wọn lóhùn pé: “Jèhófà ò já àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ kulẹ̀ rí.” Kò pẹ́ sígbà yẹn ni Arábìnrin Prisca rí oúnjẹ gbà. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn wú àwọn kan lára àwọn aládùúgbò rẹ̀ lórí, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ọlọ́run ò já ẹ kulẹ̀ lóòótọ́, torí náà a fẹ́ mọ̀ sí i nípa Ọlọ́run yẹn.” Ní báyìí, méje lára àwọn aládùúgbò Prisca ló ti ń tẹ́tí sí ìpàdé wa lórí rédíò.

 Bí òpin ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, àjálù á máa ṣẹlẹ̀ lóríṣiríṣi. (Mátíù 24:​3, 7) A mọyì ẹ̀mí ọ̀làwọ́ yín bẹ́ ẹ ṣe ń fi ìtìlẹyìn yín ránṣẹ́ láti ọ̀kan lára àwọn apá tó wà lórí ìkànnì donate.dan124.com. A máa lo ìtìlẹyìn náà láti ṣèrànwọ́ fáwọn ará wa tí àjálù dé bá.

a Ọdún iṣẹ́ ìsìn 2020 bẹ̀rẹ̀ ní September 2019, ó sì parí ní August 2020.

b Torí òfin tí ìjọba ṣe lórí àrùn Corona, àwọn ará wa ní láti gba ìwé àṣẹ kí wọ́n tó lè fi oúnjẹ ránṣẹ́ sáwọn tí àjálù dé bá. Wọ́n tún ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa kó àrùn náà.