Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Bá A Ṣe Dáàbò Bo Àwọn Tó Wá sí Ilé Ìpàdé Wa Lásìkò Àrùn Kòrónà

Bá A Ṣe Dáàbò Bo Àwọn Tó Wá sí Ilé Ìpàdé Wa Lásìkò Àrùn Kòrónà

OCTOBER 1, 2022

 Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù March 2022, ètò Ọlọ́run gbé ìròyìn kan sórí ìkànnì jw.org, pé: “Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti pinnu pé á dáa kí gbogbo ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí í kóra jọ láti jọ́sìn láwọn ilé ìpàdé wa láti ọ̀sẹ̀ April 1, láwọn àdúgbò tí kò bá ti sí òfin ìjọba tó ta ko irú ìkórajọ bẹ́ẹ̀.” Inú àwọn ará kárí ayé dùn gan-an sí ìròyìn yẹn. Àmọ́, àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà ò tíì dáwọ́ dúró. a Torí náà, àwọn àtúnṣe wo la máa ní láti ṣe, àwọn nǹkan wo la sì máa nílò ká lè dáàbò bo àwọn ará tó máa wá ṣèpàdé lójúkojú kí wọ́n má bàa kó àrùn Kòrónà? Ṣé àwọn Ilé Ìpàdé wa ṣì máa ṣeé lò lẹ́yìn ọdún méjì tá a ti ṣèpàdé níbẹ̀ kẹ́yìn?

 Ohun kan ni pé ọ̀pọ̀ oṣù ṣáájú ìgbà yẹn ni àwọn ará wa ti ń ṣètò bá a ṣe máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèpàdé ní àwọn Ilé Ìpàdé wa.

Àwọn Ìṣòro Tí Wọ́n Kojú àti Bí Wọ́n Ṣe Yanjú Wọn

 Kò ju oṣù kan tá a ṣíwọ́ láti máa ṣèpàdé láwọn Ilé Ìpàdé wa ni Ẹ̀ka Tó Ń Yàwòrán Ilé Tó sì Ń Kọ́ Ọ Lóríléeṣẹ́ (WDC) ní Warwick, New York, ti bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò ipa tí àrùn Kòrónà máa ní lórí bá a ṣe ń lo àwọn Ilé Ìpàdé wa àti ohun tá a lè ṣe kí àwọn èèyàn má bàa kó àrùn níbẹ̀.

 Ohun táwọn ará wa nílò láwọn ibì kan yàtọ̀ sóhun tí wọ́n nílò níbòmíì. Arákùnrin Matthew De Sanctis tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka WDC sọ pé: “Láwọn ilẹ̀ kan, ìṣòro wọn ni pé kò sí ohun tí wọ́n lè fi fọwọ́. Láwọn Ilé Ìpàdé tí kò ti sí omi ẹ̀rọ, wọ́n máa ní láti ra omi tàbí kí wọ́n lọ pọn omi lódò tàbí ní kànga. Láwọn orílẹ̀-èdè míì sì rèé, ìjọba ti ṣe àyípadà sí òfin nípa bí àwọn ará ìlú á ṣe máa lo ẹ̀rọ amúlétutù, ẹ̀rọ tó ń fẹ́ atẹ́gùn àti àwọn àmì tó ṣàlàyé nípa ìmọ́tótó àti ìlera.”

 Kí làwọn ará wa ṣe láti yanjú ìṣòro yìí? Arákùnrin Matthew sọ pé ọ̀pọ̀ Ilé Ìpàdé wa ló jẹ́ pé “àwọn nǹkan tí ò wọ́nwó ni wọ́n lò láti yanjú ìṣòro yìí.” Bí àpẹẹrẹ ní Papua New Guinea, wọ́n ṣètò ibi téèyàn lè ti fọwọ́, wọ́n wá gbé ike tí wọ́n fi ẹ̀rọ sí lẹ́nu tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó gálọ́ọ̀nù márùn-ún àtààbọ̀ síbẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, owó tí wọ́n ná láti ṣètò ibi téèyàn lè ti fọwọ́ láwọn Ilé Ìpàdé tó wà ní ìgbèríko jẹ́ nǹkan bí ogójì (40) dọ́là péré. Láwọn Ilé Ìpàdé wa kan nílẹ̀ Áfíríkà, wọ́n ra àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń fọwọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) láti ilẹ̀ Éṣíà.

Àwọn òbí ń fàpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn ọmọ wọn lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó

 Láwọn Ilé Ìpàdé kan, wọ́n fi kún àwọn fáànù àti ẹ̀rọ tó ń fẹ́ atẹ́gùn tó wà níbẹ̀, kí atẹ́gùn lè túbọ̀ máa wọlé dáadáa. Àwọn ìjọ kan ra ọ̀pá tó gùn tí wọ́n fi ń gbé makirofóònù kiri, kí àwọn ará má bàa máa fọwọ́ kan makirofóònù náà. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n máa ń fi oògùn apakòkòrò nu àwọn ibi táwọn èèyàn sábà máa ń fọwọ́ kàn, bí ilẹ̀kùn àti ibi tí wọ́n ti ń bu omi. Láwọn Ilé Ìpàdé kan, wọ́n fi ẹ̀rọ kan sínú ilé ìtura táá jẹ́ kí omi máa ń ṣí fúnra ẹ̀ nígbà téèyàn bá débẹ̀. Ní orílẹ̀-èdè Chile, iye owó tí wọ́n nílò láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ sí Ilé Ìpàdé kọ̀ọ̀kan tó ẹgbẹ̀rún kan àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (1,400) dọ́là.

Wọ́n ń fi ọ̀pá gbé makirofóònù káwọn èèyàn má bàa fọwọ́ kàn án

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé bí àwọn Ilé Ìpàdé wa ṣe máa wà láìséwu ló jẹ wá lọ́kàn, àwọn ará wa sapá gan-an láti ṣọ́wó ná. Bí àpẹẹrẹ láwọn ilẹ̀ kan, ìjọba ò gba owó orí lórí àwọn ohun èlò tí wọ́n fi ń fọwọ́ àti ọ̀pá tó gùn tí wọ́n fi ń gbé makirofóònù kiri. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì pawọ́ pọ̀ láti ra àwọn ohun èlò náà lọ́pọ̀, ìyẹn sì mú kí wọ́n lè ṣọ́wó ná. Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àti Ẹ̀ka Tó Ń Rajà Kárí Ayé sábà máa ń ṣètò láti ra àwọn ohun tí wọ́n nílò látọwọ́ àwọn tó ń ṣe é ní tààràtà, èyí máa ń jẹ́ kówó àwọn ọjà náà dín kù, ó sì tún máa ń jẹ́ kí wọ́n lè tètè rí àwọn ọjà náà gbà lásìkò.

Ibi tí wọ́n ti ń fi oògùn apakòkòrò sọ́wọ́

‘Ó Dá Mi Lójú Pè Kò Ní Séwu’

 Ọkàn àwọn tó ń wá sípàdé lójúkojú balẹ̀ nítorí ètò tá a ṣe káwọn èèyàn má bàa kó àrùn láwọn Ilé Ìpàdé wa. Arábìnrin Dulcine tó ń gbé ní Peru sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ẹ̀ nígbà tó gbọ́ pé a máa pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèpàdé láwọn Ilé Ìpàdé wa. Ó sọ pé: “Kí n sòótọ́, ẹ̀rù bà mí díẹ̀. Ìdí ni pé kò pẹ́ tí àrùn Kòrónà bẹ̀rẹ̀ ni mo kó àrùn náà. Torí náà, ó rí bákan lára mi láti lọ sípàdé lójúkojú, torí mo mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí n tún kó àrùn náà. Àmọ́ nígbà tí mo débẹ̀, mo rí ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn alàgbà ti ṣe láti dáàbò bò wá. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ti ṣe àwọn ibi tá a ti máa tẹ ọṣẹ apakòkòrò sọ́wọ́, wọ́n ti ra ọ̀pá gígùn tí wọ́n á fi máa gbé makirofóònù kiri, wọ́n sì tún ti ṣètò láti máa fi ọṣẹ apakòkòrò nu àwọn ibi tá a sábà máa ń fọwọ́ kàn nínú Ilé Ìpàdé wa, ká tó bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àti lẹ́yìn tá a bá parí. Gbogbo èyí ló mú kó dá mi lójú pè kò ní séwu.” b

Wọ́n ń fi oògùn apakòkòrò nu Ilé Ìpàdé

 Ìṣoro tó yàtọ̀ ni Arábìnrin Sara tó wá láti ilẹ̀ Sáńbíà ní. Ó sọ pé: “Àrùn Kòrónà ló pa ọkọ mi láwọn oṣù mélòó kan sẹ́yìn. Èmi àti ọkọ mi la jọ máa ń lọ sípàdé tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ní báyìí, mi ò mọ bó ṣe máa rí témi nìkan bá dá lọ sípàdé lójúkojú fún ìgbà àkọ́kọ́.” Ó wá ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà, ó ní: “Bí mo ṣe lọ sípàdé lójúkojú ti wá jẹ́ kí n rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Àsìkò yìí gan-an ni mo wá rí ìfẹ́ táwọn alàgbà àtàwọn ará ní sí mi, wọ́n dúró tì mí, wọ́n sì ń ràn mí lọ́wọ́.”

Inú àwọn ará ń dùn láti wá sípàdé lójúkojú

 Inú àwọn ará wa kárí ayé dùn gan-an láti pa dà sáwọn Ilé Ìpàdé wa. Ẹ ṣeun gan-an fún ìtìlẹyìn tẹ́ ẹ ṣe, púpọ̀ nínú ẹ̀ lẹ fi ránṣẹ́ látorí ìkànnì donate.dan124.com. Àwọn ọrẹ tẹ́ ẹ ṣe yìí ti mú káwọn Ilé Ìpàdé jẹ́ ibi tí kò léwu, tó sì tura.

a Níbi tó bá ti ṣeé ṣe, àwọn tí kò bá lè wá sípàdé lójúkojú ṣì lè dara pọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí lórí fóònù.

b Yàtọ̀ síyẹn, a dìídì gba àwọn tó bá wá sípàdé lójúkojú níyànjú pé kí wọ́n wọ ìbòmú.