Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

BÁ A ṢE Ń NÁ OWÓ TẸ́ Ẹ FI Ń ṢÈTỌRẸ

Jèhófà Kò Gbàgbé Àwọn Adití

Jèhófà Kò Gbàgbé Àwọn Adití

JULY 1, 2022

 Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbo èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti Ìjọba òun láìka ipò wọn sí. (1 Tímótì 2:3, 4) Ìdí nìyẹn tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń tẹ Bíbélì àti àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún onírúurú èèyàn tó fi mọ́ àwọn adití. Kódà, ètò Jèhófà ti ṣe ẹgbẹẹgbẹ̀rún fídíò ní èdè àwọn adití, a ó sì ti wà ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún (100) èdè yẹn lọ! Báwo la ṣe ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde yìí, kí la sì ń ṣe kó lè dọ́wọ́ àwọn tó nílò rẹ̀? Àwọn nǹkan wo la ti ṣe kí àwọn ìtẹ̀jáde yìí lè dáa sí i?

Báwo La Ṣe Ń Ṣe Fídíò Lédè Àwọn Adití?

 Àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè kárí ayé ló ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde lédè adití. Àwọn tó wà nínú àwùjọ atúmọ̀ èdè kọ̀ọ̀kan máa fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ìtẹ̀jáde tí wọ́n fẹ́ túmọ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wo bí wọ́n ṣe máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó máa yé àwọn tó ń sọ èdè adití, táá sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn. Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni wọ́n á ṣe fídíò ìtẹ̀jáde náà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọgọ́ta (60) àwùjọ atúmọ̀ èdè ló ń ṣiṣẹ́ déédéé láti túmọ̀ àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè àwọn adití, nígbà tí ogójì (40) àwùjọ ń ṣiṣẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan.

 Tẹ́lẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ owó ló máa ń ná wa láti ṣe fídíò lédè àwọn adití. Kámẹ́rà àti àwọn ohun èlò tá a fi ń ṣe fídíò wọ́n gan-an nígbà yẹn ju ti àsìkò yìí lọ. Bákan náà, inú yàrá ìgbohùnsílẹ̀ la ti máa ń ṣe àwọn fídíò yìí, nígbà míì ìyẹn gba pé ká tún ilé kan ṣe tàbí ká kọ́ yàrá ìgbohùnsílẹ̀ náà. Ká tó lè ṣètò gbogbo nǹkan tí àwùjọ atúmọ̀ èdè àwọn adití kan péré máa nílò, ó máa ń ná wa tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) owó dọ́là. b

 Ètò Ọlọ́run ti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan táá jẹ́ kí ọ̀nà tá à ń gbà túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wa sunwọ̀n sí i, kó sì túbọ̀ rọrùn, ìyẹn á jẹ́ ká lè fọgbọ́n ná owó táwọn ará fi ń ṣètọrẹ. Torí náà, àwọn ohun èlò ìgbàlódé tó máa ṣiṣẹ́ dáadáa, tí ò sì gbówó lórí là ń lò. Bí àpẹẹrẹ, dípò kí àwùjọ àwọn atúmọ̀ èdè lo yàrá ìgbohùnsílẹ̀, wọ́n máa ń tẹ́ aṣọ tó ní àwọ̀ ewé sára ògiri, wọ́n á sì dúró síwájú ẹ̀ tí wọ́n bá ń ṣe fídíò nínú ọ́fíìsì wọn. Tó bá jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa wà nínú fídíò kan, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin náà máa ṣe apá tó kàn wọ́n nínú fídíò yẹn láti inú ilé tàbí ọ́fíìsì wọn láìjẹ́ pé wọ́n lo yàrá ìgbohùnsílẹ̀.

 Bákan náà, a ti ṣe àwọn ètò kọ̀ǹpútà tá a ran àwọn atúmọ̀ èdè adití lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Ètò yìí ti jẹ́ kí iye àkókò tí wọ́n fi ń ṣe fídíò túbọ̀ dín kù gan-an. Àwọn ará wa sì mọrírì ètò yìí gan-an. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Alexander sọ pé: “A ti wá ń gbé àwọn fídíò lédè àwọn adití jáde ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Èyí múnú mi dùn gan-an, ojoojúmọ́ ni mo sì ń wo àwọn fídíò náà.”

 Ní báyìí, a kì í ná tó ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) owó dọ́là láti pèsè àwọn ohun tí àwùjọ atúmọ̀ èdè kan nílò. Ìyẹn ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ṣe ọ̀pọ̀ fídíò àwọn adití láwọn èdè púpọ̀ sí i.

Báwo Ni Fídíò Lédè Àwọn Adití Ṣe Ń Dọ́wọ́ Àwọn Tó Nílò Ẹ̀?

 Tí àwùjọ tó ń ṣe fídíò lédè àwọn adití bá ti parí iṣẹ́ lórí ẹ̀, ohun tó kàn ni bó ṣe máa dọ́wọ́ àwọn tó nílò ẹ̀. Tẹ́lẹ̀, ṣe la máa ń ṣe fídíò àwọn adití sórí àwo DVD àti kásẹ́ẹ̀tì onífídíò, àmọ́ ìyẹn máa ń ná wa lówó gan-an, ó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò, ó sì ń tánni lókun. Lẹ́yìn tá a bá ṣe fídíò kan, àá fi ránṣẹ́ sáwọn ilé iṣẹ́ kan láti bá wa ṣe ẹ̀dà ẹ̀. Lẹ́yìn náà, àá wá kó o ránṣẹ́ sáwọn ìjọ. Lọ́dún 2013 nìkan, a ná ohun tó ju mílíọ̀nù méjì owó dọ́là láti ṣe àwo DVD lédè àwọn adití.

 Àwọn adití mọyì ohun tí ètò Ọlọ́run ṣe yìí. Bó ti wù kó rí, bí iye àwo DVD àti kásẹ́ẹ̀tì onífídíò tá à ń ṣe ṣe ń pọ̀ sí i, ìyẹn ò jẹ́ kó rọrùn láti lò. Nígbà míì, ó máa ń gba pé ká lo ọ̀pọ̀ àwo DVD láti ṣe fídíò ìwé Bíbélì kan ṣoṣo. Arákùnrin Gilnei láti orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Nígbàkigbà tá a bá fẹ́ ka Bíbélì, a gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ wá kásẹ́ẹ̀tì tí ẹsẹ Bíbélì yẹn wà, àá tún wá ẹsẹ Bíbélì tá a fẹ́ ka, èyí kì í sì í rọrùn rárá.” Arábìnrin Rafayane tóun náà lo àwo DVD lédè àwọn adití sọ pé: “Torí ọ̀pọ̀ àkókò la fi máa ń wá àwọn ẹsẹ Bíbélì tàbí àwọn atọ́ka, ìdákẹ́kọ̀ọ́ tètè máa ń sú mi.” Tí àwọn ará bá ń lọ sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sábà máa ń kó àwọn àwo DVD tàbí kásẹ́ẹ̀tì tí wọ́n lè wò lórí tẹlifíṣọ̀n àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wọn. Àwọn arákùnrin míì tiẹ̀ máa ń gbé ohun tí wọ́n lè fi wo àwo DVD náà dání. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe ẹ̀rọ tó mọ níwọ̀n tó ṣeé wo àwo DVD, ọ̀pọ̀ àwọn ará ló sì lò ó. Arákùnrin Bobby tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Tá a bá ka ẹsẹ Bíbélì kan, tá a sì fẹ́ ka òmíì, a máa ní láti wá àwo DVD míì ká tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. Yàtọ̀ sí pé ó máa ń gba àkókò, kì í jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ lo Bíbélì tá a bá ń bá ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa sọ̀rọ̀.”

 Lọ́dún 2013, ètò Ọlọ́run gbé JW Library Lédè Àwọn Adití jáde, èyí wá jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn ará láti wa àwọn fídíò jáde lédè adití sórí fóònú tàbí tablet wọn, kí wọ́n sì máa lò ó ní tààràtà. Ètò ìṣiṣẹ́ yìí kọ́kọ́ jáde ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà. Àmọ́ ní 2017, wọ́n mú kí ètò ìṣiṣẹ́ yìí sunwọ̀n sí i, wọ́n sì fi èdè àwọn adití míì kún un. Inú àwọn ará kárí ayé dùn gan-an. Arákùnrin Juscelino tó wà ní Brazil, sọ pé: “Ó yà mí lẹ́nu gan-an! Ọ̀pọ̀ ìgbà ní mo máa ń ronú lórí bí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa adití, tí wọ́n sì fẹ́ ká sún mọ́ Jèhófà bíi tàwọn tó lè sọ̀rọ̀. Inú mi dùn gan-an, ètò ìṣiṣẹ́ yìí sì ń jẹ́ kó túbọ̀ máa wù mi láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Wọ́n ń lo JW Library Lédè Àwọn Adití

 Ní báyìí, à ń gbé gbogbo fídíò tá à ń ṣe lédè àwọn adití jáde lórí ìkànnì wa àti lórí JW Library Lédè Àwọn Adití. Nípa bẹ́ẹ̀, a ti lè túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde lédè àwọn adití, ká gba fídíò ẹ̀ sílẹ̀, kó sì dọ́wọ́ àwọn ará láàárín ọjọ́ díẹ̀ dípò ọ̀pọ̀ oṣù tàbí ọdún tó máa ń gbà tẹ́lẹ̀. Kódà, ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde lédè àwọn adití ló jẹ́ pé bí tàwọn tó lè sọ̀rọ̀ ṣe ń jáde ni tiwọn náà ń jáde.

 Ẹ jẹ́ ká gbọ́ díẹ̀ lára ohun táwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin tó jẹ́ adití sọ. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Klízia sọ pé: “Mi ò tíì rí ètò míì tó dà bí èyí, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn adití, tí wọ́n sì ṣe tan láti pèsè àwọn ohun táá jẹ́ kó rọrùn fún wa láti sún mọ́ Ọlọ́run lọ́nà tó rọrùn. Kò sì nǹkan náà láyé yìí tá a lè fi wé ohun tí ètò Ọlọ́run ṣe fún wa.” Vladimir sọ pé: “Àwọn fídíò yìí jẹ́ kí n rí i pé bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn tó lè sọ̀rọ̀ náà ló ṣe nífẹ̀ẹ́ àwa adití, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún.”

 Ìsọfúnni kan sábà máa ń wà láwọn fídíò lédè àwọn adití pé: “Ìtẹ̀jáde yìí jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń fi ọrẹ àtinúwá tì lẹ́yìn.” A mọrírì owó tẹ́ ẹ fi ń ṣètìlẹyìn, ọ̀pọ̀ nínú ẹ̀ ló sì jẹ́ pé orí ìkànnì donate.dan124.com lẹ ti ń ṣe é. Owó yìí la fi ń tẹ Bíbélì àtàwọn nǹkan míì tó ń mú kí gbogbo èèyàn sún mọ́ Ọlọ́run títí kan àwọn tó ń sọ èdè adití.

a Torí pé ọwọ́ àti ìrísí ojú làwọn adití fi máa ń sọ̀rọ̀, orí fídíò la máa ń ṣe àwọn ìtẹ̀jáde wọn sí dípò ìwé.

b Dọ́là owó Amẹ́ríkà la ní lọ́kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí.