Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ | ỌMỌ TÍTỌ́

Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Jẹ́ Bàbá Rere

Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Jẹ́ Bàbá Rere

 Kí ni ojúṣe bàbá nínú ìdílé?

  •   Kẹ́ ẹ tó bímọ. Irú ọkọ tó o bá jẹ́ báyìí náà ni irú bàbá tó o máa dà tó bá yá. Ìwé Do Fathers Matter? sọ pé:

     “Tí ọkọ kan bá ń ran ìyàwó ẹ̀ tó lóyún lọ́wọ́, tó ń bá a ra ohun tó nílò, tó ń gbé e lọ sọ́dọ̀ dókítà, tó sì máa ń gbé etí síbi ikùn ìyàwó ẹ̀ láti máa gbọ́ bí ọmọ náà ṣe ń yíra, ó ṣeé ṣe kí irú ọkọ bẹ́ẹ̀ máa ran ìyàwó ẹ̀ lọ́wọ́ láti tọ́ ọmọ náà lẹ́yìn tí wọ́n bá bí i.”

     “Mo máa ń ran ìyàwó mi lọ́wọ́ nígbà tó wà nínú oyún kò má bàa dà bíi pé ó dá wà. Kódà, a jọ to yàrá tí ọmọ náà máa wà. Bí àwa méjèèjì ṣe pawọ́ pọ̀ ṣiṣẹ́ yìí jẹ́ kó dùn gan-an, a ò lè gbàgbé àsìkò yẹn láé.”​—James.

     Ìlànà Bíbélì: ‘Ẹ máa wá ire àwọn ẹlòmíì, kì í ṣe tiyín nìkan.’​—Fílípì 2:4.

  •   Lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá bímọ. Tó o bá ń gbé ọmọ rẹ, tó o sì ń bá a ṣeré látìgbàdégbà, ẹ̀ẹ́ túbọ̀ sún mọ́ra. Máa ran ìyàwó ẹ lọ́wọ́ láti tọ́jú ọmọ náà. Bó o ṣe ń sapá láti tọ́jú ọmọ rẹ máa ṣe ọmọ náà láǹfààní bó ṣe ń dàgbà. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti tọ́jú ọmọ rẹ, ìyẹn á fi hàn pé ọmọ náà ṣeyebíye sí ẹ.

     “Máa bá ọmọ rẹ ṣeré dáadáa. Máa rẹ́rìn-ín, má sì jẹ́ kí nǹkan máa ká ẹ lára jù. Rántí pé, ọ̀dọ̀ ìwọ tó o jẹ́ òbí lọmọ rẹ ti máa kọ́kọ́ mọ ohun tí wọ́n ń pè ní ìfẹ́.”​—Richard.

     Ìlànà Bíbélì: “Àwọn ọmọ jẹ́ ogún láti ọ̀dọ̀ Jèhófà; èso ikùn jẹ́ èrè.”​—Sáàmù 127:3.

  •   Bí ọmọ rẹ ṣe ń dàgbà. Ìwádìí fi hàn pé àwọn ọmọ tó bá sún mọ́ bàbá wọn máa ń ṣe dáadáa nílé ìwé, wọn kì í sábà ní ẹ̀dùn ọkàn, kò sì wọ́pọ̀ kí wọ́n máa lo oògùn olóró tàbí kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwàkiwà. Torí náà, wáyè láti sún mọ́ ọmọ rẹ, kó o lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú ẹ̀.

     “Ọmọ mi sọ fún mi pé lára ohun tóun ò lè gbàgbé láé tóun bá kúrò nílé ni àwọn ọ̀rọ̀ tá a jọ máa ń sọ tá a bá jọ wà nínú mọ́tò tàbí tá à ń jẹun alẹ́. Kódà, àwọn àsìkò tí mi ò lérò la sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì jù. Ohun tó sì fà á ni pé, a sábà máa ń wà pa pọ̀.”​—Dennis.

     Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe bí aláìlọ́gbọ́n àmọ́ bí ọlọ́gbọ́n, kí ẹ máa lo àkókò yín lọ́nà tó dára jù lọ.”​—Éfésù 5:15, 16.

 Kí nìdí tí ojúṣe bàbá fi ṣe pàtàkì nínú ìdílé?

 Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé ojúṣe bàbá ni láti pèsè ohun tí wọ́n máa nílò nínú ìdílé, kí wọ́n sì dáàbò bo ìdílé wọn. Wọ́n sì gbà pé ìyà ló sábà máa ń mára tu àwọn tó wà nínú ìdílé. (Diutarónómì 1:31; Àìsáyà 49:15) Àmọ́ nínú àwọn ìdílé míì, ìyá ló máa ń ṣe ojúṣe bàbá, bàbá sì máa ń ṣe ti ìyá. Èyí ò wù kó jẹ́, àwọn olùṣèwádìí sọ pé iṣẹ́ àwọn méjèèjì ṣe pàtàkì gan-an, bí wọ́n sì ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ lá jẹ́ kí wọ́n lè tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú. a

 Judith Wallerstein tó máa ń ṣèwádìí nípa ìdílé sọ ìrírí ara ẹ̀. Ó ní: “Nígbà tí mọ́tò gbá ọmọ mi tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá (12), ó fẹ́ kí bàbá òun wà pẹ̀lú òun nínú ọkọ̀ tó gbé òun lọ sílé ìwòsàn torí ó mọ̀ pé wọ́n máa dáàbò bo òun. Nígbà tó yá, èmi ló fẹ́ kí n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì òun nílé ìwòsàn kí n lè máa mára tù ú.” b

 “Bàbá lè dáàbò bo àwọn tó wà nínú ìdílé, kó sì mú kí nǹkan máa lọ geerege. Àwọn nǹkan yìí lè ṣòro fún ìyá kan láti ṣe lóun nìkan. Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìyá máa ń jẹ́ kára tu àwọn ọmọ torí pé ó máa ń fi sùúrù tẹ́tí sí wọn. Àmọ́, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àwọn méjèèjì ló ń mú kí nǹkan lọ dáadáa nínú ilé.”​—Daniel.

 Ìlànà Bíbélì: “Ọmọ mi, fetí sí ìbáwí bàbá rẹ, má sì pa ẹ̀kọ́ ìyá rẹ tì.”​—Òwe 1:8.

 Ipa táwọn bàbá ń kó nínú ìgbésí ayé àwọn ọmọbìnrin wọn

 Ara ẹ̀yin bàbá làwọn ọmọbìnrin ti máa ń kọ́ bó ṣe yẹ káwọn ọkùnrin máa ṣe sí wọn. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà méjì tí wọ́n máa ń gbà kọ́ ẹ̀kọ́ yìí:

  •   Wọ́n máa ń kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe sí ìyá wọn. Tó o bá nífẹ̀ẹ́ ìyàwó ẹ, tó o sì ń bọ̀wọ̀ fún un, ìyẹn á jẹ́ kí ọmọbìnrin ẹ mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó máa wò lára ọkùnrin tó máa fẹ́ lọ́jọ́ iwájú.​—1 Pétérù 3:7.

  •   Wọ́n máa ń kíyè sí bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe sí àwọn fúnra wọn. Tó o bá ń buyì kún ọmọbìnrin rẹ, ìyẹn á jẹ́ kóun náà níyì lójú ara ẹ̀, kò sì ní gbàgbàkugbà táwọn ọkùnrin míì bá ń fi ìwọ̀sí lọ̀ ọ́.

     Lọ́wọ́ kejì, tó bá ti mọ́ bàbá kan lára láti máa sọ̀rọ̀ sí ọmọbìnrin ẹ̀, ọmọ náà lè máa wo ara ẹ̀ bí ẹni tí ò wúlò. Ìyẹn lè mú kó máa wá ọkùnrin táá máa sọ̀rọ̀ dídùn fún un, àwọn ọkùnrin náà sì lè má ní ire ẹ̀ lọ́kàn.

     “Tí bàbá kan bá ń fìfẹ́ hàn sí ọmọbìnrin ẹ̀, ọkùnrin kankan ò ní lè fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn án, pàápàá ọkùnrin tí ò níwà ọmọlúàbí.”​—Wayne.

a Ọ̀pọ̀ àwọn ìyá ni wọ́n ti dá tọ́ àwọn ọmọ wọn yanjú.

b Látinú ìwé The Unexpected Legacy of Divorce.