Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ọmọ Títọ́

Bó O Ṣe Lè Tọ́ Ọmọ Yanjú

Ohun Tó O Lè Ṣe Kó O Lè Jẹ́ Bàbá Rere

Irú ọkọ tó o bá jẹ́ báyìí náà ni irú bàbá tó o máa dà lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá bímọ.

Ohun Tó Yẹ Kí Àwọn Òbí Mọ̀ Nípa Jẹ́lé-Ó-Sinmi

Bí ara rẹ ní ìbéèrè mẹ́rin kó o fi lè mọ̀ bóyá ó yẹ kó o gbé ọmọ ẹ lọ sí jẹ́lé-ó-sinmi.

Báwo Lo Ṣe Lè Jẹ́ Òbí Rere?

Báwo lo ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ rẹ yanjú?

Ṣó Yẹ Kí Ọmọ Mi Ní Fóònù?

Bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí kó o lè mọ̀ bóyá ìwọ àti ọmọ rẹ ti ṣe tán láti bójú tó ojúṣe náà.

Kọ́ Àwọn Ọmọdé Bí Wọ́n Ṣe Lè Máa Fọgbọ́n Lo Fóònù

Àwọn ọmọdé tó mọ tìfun-tẹ̀dọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé nílò kí àwọn òbí kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè lo fóònù lọ́nà tó dára.

Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Ohun Tó Ń Mú Ọkàn Fà sí Ìṣekúṣe

Àwọn òbí kan rò pé ó máa ṣòro gan-an kí ọmọ kan tó lè rí àwòrán ìṣekúṣe, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ohun tó yẹ kó o mọ̀ àtohun tó yẹ kó o ṣe kó ò lè dáàbò bo ọmọ rẹ.

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé—Apá Kìíní: Ìwé Kíkà Tàbí Ìran Wíwò?

Ọ̀pọ̀ ọmọdé máa ń fẹ́ wo fídíò. Báwo làwọn òbí ṣe lè mú káwọn ọmọ túbọ̀ máa kàwé?

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Káwọn Ọmọdé Máa Kàwé​—Apá 2: Ti Orí Ẹ̀rọ Tàbí Tinú Ìwé?

Ṣé ìwé orí ẹ̀rọ ló dá a káwọn ọmọ máa kà, tàbí torí bébà? Méjèèjì ló láǹfààní.

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Ìròyìn Tó Ń Jáni Láyà

Kí ni àwọn òbí lè ṣe tí ìròyìn ò fi ní máa dẹ́rù ba àwọn ọmọ wọn?

Ìdílé Aláyọ̀​—Àpẹẹrẹ Rere

Tó o bá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ gbọ́ràn sí ẹ lẹ́nu, o gbọ́dọ̀ máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn.

Ohun Tí Ẹ Lè Ṣe Tí Ọmọ Yín Bá Jẹ́ Abirùn

Jẹ́ ká wo àwọn ìṣòro mẹ́ta tó sábà máa ń jẹ yọ àti bí ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ṣe lè mú kó o borí wọn.

Ìdálẹ́kọ̀ọ́

Àǹfààní Tó Wà Nínú Eré Táá Mú Kí Ọmọdé Ronú

Àǹfààní tó wà níbẹ̀ pọ̀ ju ti àwọn nǹkan téèyàn dìídì ṣètò tàbí kéèyàn kan máa fi tẹlifíṣọ̀n dára yá.

Iṣẹ́ Ilé Ṣe Pàtàkì

Ẹ̀yin òbí, ṣé ó máa ń ṣe yín bíi pé kẹ́ ẹ má ṣe yan iṣẹ́ ilé kankan fún àwọn ọmọ yín? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kà nípa bí iṣẹ́ ilé ṣe máa mú kí àwọn ọmọ yín ní ìwà àgbà tó sì máa mú kí wọ́n láyọ̀.

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Ilé Bá Sú Ọmọ Mi?

Tí ọmọ ẹ ò bá jáde nílé, tí kò sì rí nǹkan ṣe, wo àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́.

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Níwà Ọmọlúwàbí Lóde Òní

Ṣàyẹ̀wò kókó mẹ́ta tó lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti máṣe níwà ìmọtara-ẹni-nìkan.

Kọ́ Àwọn Ọmọ Rẹ Láti Máa Moore

Ẹ lè kọ́ àwọn ọmọdé pàápàá láti máa dúpẹ́ bí ẹnì kan bá fún wọn lẹ́bùn tàbí tó ṣe wọ́n lóore.

Ìdí Tí Ìwà Ọmọlúwàbí Fi Ṣe Pàtàkì

Tó o bá ń kọ́ àwọn ọmọ rẹ ní ìwà ọmọlúwàbí, ọjọ́ ọ̀la wọn máa dára gan-⁠an.

Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbára Lé

Ìgbà wo ló yẹ kí òbí ti kọ́ ọmọ láti dẹni tó ṣeé gbára lé, ṣé nígbà tó ṣì wà lọ́mọdé ni àbí tó bá ti dàgbà?

Bí O Ṣe Lè Máa Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ìbáwí kọjá kéèyàn kàn máa ṣòfin, kó sì máa fìyà jẹ ẹni tó bá rú u.

Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìforítì

Tí àwọn ọmọ bá kọ́ láti ní ìforítì, ó máa jẹ́ kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro lọ́jọ́ iwájú.

Bí A Ṣe Lè Ran Awọn Ọmọ Lọ́wọ́ Láti Borí Ìjákulẹ̀

Gbogbo èèyàn ló máa ń ní ìjákulẹ̀. Kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti fojú tó dáa wo ìjákulẹ̀, kó o sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ojútùú.

Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Máàkì Rẹ̀ Lè Gbé Pẹ́ẹ́lí

Wo bó o ṣe lè mọ ohun tó fà á gan-an tí ọmọ rẹ fi ń gbòdo wálé, kó o sì jẹ́ kó máa wù ú láti kẹ́kọ̀ọ́.

Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Wọ́n Bá Ń Halẹ̀ Mọ́ Ọmọ Mi?

Wo ohun mẹ́rin tó o lè ṣe láti kọ́ ọmọ ẹ bó ṣe lè kápá ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ọn.

Bó O Ṣe Lè Ran Ọmọ Rẹ Tó Ń Bàlágà Lọ́wọ́

Ìmọ̀ràn márùn-ún pàtàkì tá a mú látinú Bíbélì lè mú kí àsìkò ìbàlágà náà rọrùn.

Bi O Se Le Salaye Ohun Ti Iku Je fun Omo Re

Ohun merin to o le se lati dahun ibeere won, ta a si mu ki won fara da a ti eni ti won feran ba ku.

Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà

O máa dáàbò bo ọmọ rẹ tó o bá bá a sọ̀rọ̀ nípa ìkórìíra tí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà máa ń fà ní ìbámu pẹ̀lú ọjọ́ orí rẹ̀.

Báwo Ni Àwọn Òbí Ṣe Lè Kọ́ Àwọn Ọmọ Wọn Nípa Ìbálòpọ̀?

Bíbélì ni àwọn ìlànà tó wúlò táá jẹ́ kó o lè bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ kó o sì tún lè dáàbò bo wọ́n lọ́wọ́ àwọn tó ń bọ́mọdé ṣèṣekúṣe.

Kọ́ Ọmọ Rẹ Nípa Ìbálòpọ̀

Àwọn ọmọdé ti wá ń kó sínú ewu ìbálòpọ̀ ju àtẹ̀yìnwá lọ. Kí ni ohun tó yẹ kó o mọ̀, kí lo sì lè ṣe láti dáàbò ọmọ rẹ̀?

Dáàbò Bo Ọmọ Rẹ

Wọ́n kọ́ Kọ́lá àti Tósìn ní ohun tí wọ́n lè ṣe kí wọ́n má bàa kó sínú ewu.

Bó O Ṣe Lè Bá Ọmọ Ẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ọtí

Ìgbà wo ló yẹ káwọn òbí bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ nípa ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí, báwo ló sì ṣe yẹ kí wọ́n bá wọn sọ ọ́?

Ìbáwí

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀

Ran ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó má sì ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ.

Bí O Ṣe Lè Bá Àwọn Ọmọ Rẹ Wí

Bíbélì sọ ohun mẹ́ta tó máa mú kí ìbáwí yọrí sí rere.

Bó O Ṣe Lè Kọ́ Ọmọ Rẹ Láti Máa Gbọ́ràn

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé gbogbo ìgbà ni ọmọ rẹ máa ń kọ ọ̀rọ̀ sí ẹ lẹ́nu, kí lo lè ṣe? Ohun márùn-ún wà tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Kéèyàn Máa Kó Ara Rẹ̀ Níjàánu

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa kó ara wa níjàánu, báwo la sì ṣe lè ṣe é?

Kọ́ Ọmọ Rẹ Ní Ìrẹ̀lẹ̀

Tó o bá kọ́ ọmọ rẹ láti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó máa ṣe é láàǹfààní ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú.

Bó O Ṣe Lè Bójú Tó Ọmọ Tó Ń Ṣe Ìjọ̀ngbọ̀n

Kí lo lè ṣe tí ọmọ rẹ bá bẹ̀rẹ̀ ìjọ̀ngbọ̀n? Àwọn ìlànà Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti borí ìṣòro yìí.

Tí Ọmọ Rẹ Bá Ń Purọ́

Kí ló yẹ kó o ṣe bí ọmọ rẹ bá ń purọ́? Àpilẹ̀kọ yìí fún wa ní ìmọ̀ràn Bíbélì lórí bó o ṣe lè kọ́ ọmọ rẹ láti máa sọ òtítọ́.