Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Bọ́rọ̀ Ṣe Rí Lára Àwọn Tó Ń Bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣiṣẹ́ ní Warwick

Bọ́rọ̀ Ṣe Rí Lára Àwọn Tó Ń Bá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣiṣẹ́ ní Warwick

Ẹnu ya ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tí wọ́n rí i báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe yọ̀ǹda ara wọn níbi iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe ní Warwick. Ọ̀gá iléeṣẹ́ tó ṣe àwọn ẹ̀rọ agbéniròkè síbi àwọn ilé tí wọ́n ń kọ́ sọ fún òṣìṣẹ́ kan pé: “Iṣẹ́ ńlá ni ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ṣiṣẹ́ níbí ń ṣe o. Ṣàṣà lẹni tó lè yọ̀ǹda àkókò rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ lóde òní.”

Nígbà tí ọ̀gbẹ́ni yìí àtàwọn míì kọ́kọ́ gbọ́ pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ló pọ̀ jù nínú àwọn tó ń ṣiṣẹ́ níbi oríléeṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń kọ́ sí Warwick, nílùú New York, pé wọn ò gbowó iṣẹ́, gbogbo èrò ọkàn wọn ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé lágbègbè yẹn ló yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ lópin ọ̀sẹ̀ nìkan. Ẹnu yà wọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé káàkiri orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà làwọn èèyàn ti wá, ṣe ni wọ́n fiṣẹ́ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè wá fi oṣù díẹ̀ ṣiṣẹ́ níbẹ̀, àwọn míì tiẹ̀ ti lo ọdún mélòó kan.

Nígbà tọ́dún 2015 fi máa parí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógún (23,000) ló ti yọ̀ǹda ara wọn láti bá àwọn ìdílé Bẹ́tẹ́lì lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ṣiṣẹ́ ní Warwick. Nǹkan bíi ọgọ́rùn-ún méje ó lé àádọ́ta (750) àwọn agbaṣẹ́ṣe tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tún ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ kí iṣẹ́ má bàa falẹ̀. Ohun tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn agbaṣẹ́ṣe yìí rí bí wọ́n ṣe ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣiṣẹ́ wú wọn lórí gan an.

Ibi Iṣẹ́ Tó Ń Tuni Lára

Ọ̀gá iléeṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń ṣe wíńdò, tí wọ́n sì ń ṣe ògiri ilé lọ́ṣọ̀ọ́ kọ̀wé pé: “Ẹnu ń ya gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ wa tó wá ṣiṣẹ́ níbí sí bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń bá ṣiṣẹ́ ṣe ń hùwà. Ìwà wọn yìí ló ń wú ọ̀pọ̀ nínú wa lórí tá a fi fẹ́ máa bá wọn ṣiṣẹ́.”

Àwọn òṣìṣẹ́ tún wá láti iléeṣẹ́ míì láti bá wa kọ́ àwọn ilé gbígbé dókè. Nígbà tí wọ́n parí iṣẹ́ wọn, mẹ́ta lára àwọn òṣìṣẹ́ iléeṣẹ́ yìí ló sọ pé àwọn ò lọ, pé àwọn á máa bá wa ṣiṣẹ́ ìkọ́lé lọ ní Warwick. Wọ́n fiṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe níléeṣẹ́ wọn sílẹ̀, wọ́n wá ń bá iléeṣẹ́ míì tó ṣì ń bá wa kọ́lé ṣiṣẹ́.

Ìwà tó yẹ Kristẹni táwọn Ẹlẹ́rìí ń hù nípa rere lórí àwọn kan tó ń bá wọn ṣiṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan bá iléeṣẹ́ tó bá wa kọ́ ìpìlẹ̀ àwọn ilé náà ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ oṣù mélòó kan ní Warwick, ìyàwó ẹ̀ rí i pé ìwà ẹ̀ ti yàtọ̀ pátápátá, ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ̀ sì ti dáa nínú ilé. Inú ẹ̀ dùn, ó sọ pé, “Àfi bíi pé kì í ṣe ọkọ tí mo fẹ́ nìyẹn!”

‘Àwọn Obìnrin Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Ń Bọ̀’

Obìnrin ló pọ̀ jù nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń ṣiṣẹ́ níbi ìkọ́lé náà. Wọ́n máa ń wa bọ́ọ̀sì, wọ́n máa ń tún yàrá ṣe, wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ akọ̀wé. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n máa ń darí àwọn ọkọ̀ gba ibi tó yẹ, wọ́n máa ń wa àwọn katakata ńlá, wọ́n máa ń so wáyà iná pọ̀, wọ́n máa ń fi nǹkan wé páìpù kí omi má bàa dì sínú rẹ̀, wọ́n máa ń ṣe ohun tí wọ́n fi ń bo ara ilé, wọ́n sì máa ń lẹ̀ ẹ́ mọ́ ògiri inú ilé àti òrùlé, wọ́n ń ṣiṣẹ́ púlọ́ńbà, wọ́n sì ń da kọnkéré. Iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn obìnrin yẹn ń ṣe.

Ọ̀gbẹ́ni kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tó wá ṣe òrùlé sọ pé òun kíyè sí i pé tí bọ́ọ̀sì bá gbé àwọn èèyàn dé, tí wọ́n wá ń bọ́ọ́lẹ̀, ṣe làwọn tọkọ taya kan máa ń dira wọn lọ́wọ́ mú bí wọ́n ṣe ń rìn lọ síbi iṣẹ́. Ohun tó rí yẹn wú u lórí gan-an. Ó sì rí i pé àwọn obìnrin ń ṣiṣẹ́ kára níbi iṣẹ́ ìkọ́lé náà. O sọ pé, “Téèyàn bá kọ́kọ́ rí àwọn obìnrin yìí, ẹ máa rò pé wọ́n kàn sin ọkọ wọn wá síbi iṣẹ́ ni. Àmọ́ wọ́n ń ṣe dẹndẹ iṣẹ́! Àìmọye iṣẹ́ ìkọ́lé ni mo ti ṣe káàkiri ìlú New York, àmọ́ ti ibí yìí yàtọ̀. Mi ò rí irú ẹ̀ rí.”

Níparí ọdún 2014 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2015, òtútù tó mú le gan-an, ó sì lè fẹ́ mú kí àwọn èèyàn jókòó sílé dípò kí wọ́n jáde síta wá máa ṣiṣẹ́. Ọ̀gbẹ́ni Jeremy tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́lé náà sọ pé: “Mo rántí pé láwọn ọjọ́ míì tí òtútù bá mú gan-an, ọ̀gá iṣẹ́ kan tó ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀kan lára àwọn iléeṣẹ́ tó ń bá wa kọ́ àwọn ìpìlẹ̀ ilé máa ń bi mí pé, ‘Ṣé àwọn obìnrin yín máa ṣiṣẹ́ lọ́la ṣá?’

“‘Bẹ́ẹ̀ ni.’

“‘Àtàwọn tó ń darí ọkọ̀ níta gbangba náà?’

“‘Bẹ́ẹ̀ ni.’

“Nígbà tó yá, ó sọ fáwọn ọmọọṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n yáa wá síbi iṣẹ́ o, torí pé àwọn obìnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí pàápàá ń bọ̀!”

Àwọn Tó Ń Wa Bọ́ọ̀sì Gbádùn Iṣẹ́ Wọn

Wọ́n gba àwọn tó lé ní márùndínlógójì (35) pé kí wọ́n máa wa bọ́ọ̀sì táá máa gbé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti ilé tí wọ́n ń gbé lọ síbi iṣẹ́ ní Warwick, kí wọ́n sì gbé wọn pa dà.

Lọ́jọ́ kan tí awakọ̀ kan fẹ́ gbé wọn, ó kọ́kọ́ dìde dúró, ó kọjú sí àwọn tó wà nínú mọ́tò, ó wá sọ pé, “Mo fẹ́ràn láti máa wa ẹ̀yin ajẹ́rìí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ sọ fún ọ̀gá mi pé kí wọ́n jẹ́ kí n máa bá yín ṣiṣẹ́ lọ. Ohun tẹ́ ẹ ti kọ́ mi nípa Bíbélì ti pọ̀ gan-an. Kí n tó mọ ẹ̀yin ajẹ́rìí, mi ò mọ orúkọ Ọlọ́run, mi ò sì mọ̀ pé ayé máa di párádísè. Ẹ̀rù ikú ò bà mí mọ́ báyìí. Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí múnú mi dùn gan-an o. Mo fi dá yín lójú pé màá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́jọ́ tí mi ò bá tún ti lọ síbi iṣẹ́.”

Damiana, tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ṣiṣẹ́ ní Warwick sọ pé: “Nígbà tá a wọnú bọ́ọ̀sì tán lọ́jọ́ kan, ọkùnrin tó fẹ́ wà wá sọ pé òun lọ́rọ̀ tóun fẹ́ bá wa sọ. Ó ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) àwọn Ẹlẹ́rìí lòun ti gbé lọ gbé bọ̀ láti àwọn iléeṣẹ́ wa tó wà nílùú New York. Ó ní, ‘Kò sẹ́ni tí kò ní tiẹ̀ lára o, àmọ́ ẹ̀yin máa ń fìfẹ́ bára yín lò, ẹ sì máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ohun tó dáa ni.’ Ó tún sọ pé òun fẹ́ràn láti máa bá wa sọ̀rọ̀.

“Nígbà tó sọ̀rọ̀ tán, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú bọ́ọ̀sì náà bi í pé, ‘Ṣé ẹ máa ń gbádùn àwọn orin tá a máa ń kọ?’

“Ló bá bú sẹ́rìn-ín, ó sì sọ pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni! Ṣé ká kọ orin 134?’” *

^ ìpínrọ̀ 22 Orin 134 wà nínú ìwé Kọrin sí Jèhófà, àkòrí rẹ̀ ni “Fojú Inú Wo Ìgbà Tí Gbogbo Nǹkan Yóò Di Tuntun.” Ó dá lórí bí inú àwọn tó bá wà nínú ayé tuntun Ọlọ́run ṣe máa dùn tó.